Osinbajo Crisis: Ìbéèrè mẹ́rin ti Laolu Akande ń bèèrè lọ́wọ́ Festus Adedayo

Yemi Osinbajo ati Muhammadu Buhari Image copyright @akandeoj

Agbẹnúsọ fun ìgbákeji ààrẹ Ọjọgbọ́n Yemi Osinbajo, Laolu Akande ti ni àsìgbọ́ ọ̀rọ̀ ni o, Osinbajo kò gbàdúra ikú fún ààrẹ Muhammadu Buhari lásìkò to lọ ẹka ìjọ ìràpadà RCCG.

Wọ́n fi ẹsun kan pé Osinbajo àti àwọn ọmọ ijọ náà pe wọn ń gbadúra pé ki ààrẹ Buhari ku.

Laolu Akande lo ń fèsì sí àpilẹkọ kan ti Festus Adedayo kọ apilẹkọ kan to kọ jade nínú ọ̀pọ̀ iwé ìròyìn lórí ayelujára lọ́jọ́ ajé to pe akọle rẹ ni "The Trials of Brother Osinbajo".

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adedayọ lo sọ pé wọ́n bú oun gbọ́ pé Osinbajo, to jẹ Olusọ-aguntan àgbà ninu ijọ RCCG lo ń gbadura pẹ̀lú àwọn ọmọ ijọ rẹ̀ pe, ki ààrẹ Buhari kú lásìkò to gbàyè lọ fun ìtọjú ara rẹ̀ loke okun.

Alápilẹkọ náà sọ pé, ọrẹ tímọtímọ ààrẹ Buhari tó wà nínú ìpejọpọ náà lo sàlàye fun ààrẹ, nipa ìpínnu ìgbákeji rẹ, èyí si lo fa gbọ́nmi-si-omi-oto

tó wà láàrin ààrẹ àti igbákeji rẹ.

Image copyright Osinbajo/instagram
Àkọlé àwòrán Ìbéèrè mẹ́rin ti Laolu Akande bèrè lọ́wọ́ Festus Adedayo

Ẹ̀wẹ̀, oluranlọwọ pàtàki si igbákeji ààrẹ feto iroyin ni ki Adedayo sàlàyé ẹka ìjọ RCCG naa àti ọjọ ti àdúra náà wáye gẹ́gẹ́ bo ṣe fẹ̀sùn kan igbakeji aarẹ.

Níbo gan ni nipinlẹ Ogun? gẹ́gẹ́ bi o ṣe sọ pé nígbà ti ìgbákeji ààrẹ lọ ilú rẹ̀ ni ọrọ naa ṣẹlẹ̀, ati pe ki o pésé fọnràn aworan tàbi ohùn ti wọ́n gbà silẹ̀ bí ẹ̀rí.

Awọn wo ni èèyan jànkanjakan ti wọ́n wà nibẹ̀ ti wọn si le jẹ́ri síí, Ki ni orúkọ wọ́n?

Image copyright Osinbajo/instagram
Àkọlé àwòrán Osinbajo kò gbàdúrà ikú fún Buhari -Laolu Akande

Ta ni ọrẹ tímọ-timọ Buhari to wà níbẹ̀, to dédé sàbẹ̀wò sí ààrin wọn, to si mú ẹri wá fún ààrẹ?

Akande ní, o ṣe ni láànú pé àwọn kan n fíra wọn silẹ̀ láti jẹ oun èlò àyálo, ti yóò da omi àláfíà to wà láàrin ààrẹ Buhari ati Igbákeji rẹ̀ Yemi Osinbajo ru.