Lagos-Ibadan: Èèyàn mẹ́tàlá dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ lọ́nà Ìbàdàn sí ÈKó

Awọn ọkọ ti ijamba naa ṣẹlẹ si Image copyright others
Àkọlé àwòrán Lara awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ ni okunrin mẹrin, obinrin meje ati ọmọde meji

Ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC sọ pe, ijamba ọkọ to waye lopopona Ibadan si ilu Eko ti mu ẹmi eeyan mẹtala lọ.

Agbegbe Ṣapade ni ilu Ogere ni ipinlẹ Ogun ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Alukoro FRSC, Florence Okpe sọ fun awọn akọroyin pe, ijamba naa ṣẹlẹ ni nkan bi aago meje irọlẹ, ni agbegbe ti ileeṣẹ to n tun opopona ṣe ti pin ọna si meji.

Okpe sọ pe: Awọn mẹtadinlogoji ni ijamba naa kan, okunrin ogun, obirin mẹẹdogun ati ọmọde meji."

Florence ṣalaye pe awọn mẹwaa lo ṣeṣe ninu ijamba ọkọ ọhun, ọkunrin mẹrin ati obinrin mẹfa.

Lara awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ ni okunrin mẹrin, obinrin meje ati ọmọde meji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMakinde vs Adelabu: Makinde ní ìjọba Ọyọ yàtọ̀ sí ti Ọṣun àbí Ekiti tí APC lé dànù

Ijamba naa ṣẹlẹ nigba ti taya ọkọ akoyọyọ kan, to n sare asapajude fọ lojiji, to si fori sọ ọkọ akero meji ti ohun naa n sare loju popo ọhun.

ere asapajude lai bọwọ fun gbendeke kilomita aadọta ere sisa lo tun ṣakoba to pọ ninu ijamba naa.

Nomba ọkọ akero naa ni Mazda KTU 93 XW ati bọọsi Toyota KEY 847 XA

Ọga agba FRSC ipinlẹ Ogun, Clement Oladele ni ijamba naa jẹ eyi to bani ninu jẹ pupọ, o si ba ẹbi awọn to jẹ Ọlọrun nipe kẹdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí

Ileeṣẹ FRSC ti gbe oku awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ si ile igbokusi to wa ni Ipara, ni ipinlẹ Ogun.

O ni awọn ti wọn n gb aitọju wa ni ile iwosan Victory to wa nilu Ogere

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo Bullet, ọmọ ọdun mẹjọ tó fẹ́ lùwẹ̀ wọ Olympics

Bakan naa lo tun ran awọn awakọ leti lati tẹlẹ aṣẹ ere sisa oni kilomita aadọta loju opopona ti wọn n tunṣe naa titi wọn yoo fi pari iṣẹ nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAeroplane House: Látọdún 1999 ni mo ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé yìí fún ìyàwó mi ọ̀wọ́n