Busola Dakolo: Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ yàtò sí ǹkán tó sẹ̀lẹ̀ ní

Biodun Fatoyinbo àti Busola Dakolo Image copyright @BIODUNFATOYINBO/@BUSOLADAKOLO
Àkọlé àwòrán Pasitọ Biodun Fatoyinbo àti Busola Dakolo

Agbẹjọro fun Busola Dakolo ti ni awọn n gbe Biodun Fatoyinbo lọ si ile ọjọ kotẹmilọrun lẹyin ti ile ẹjọ da ẹjọ ifipanilopọ to pe mọ danu.

Agbẹjọrọ Pelumi Olajengbesi to ba ikọ BBC sọrọ sọ wi pe ile ẹjọ kọ lati gbẹ ẹjọ naa yẹwo nitori ọjọ ti lọ lori idajọ naa.

Olajengbesi ni awọn n lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun ni ireti pe wọn yoo gbe ọrọ naa yẹwo daadaa lati se oun to tọ.

O ni awọn ni igbagbọ pe ile ẹjọ naa yoo se oun to tọ ju nkan ti ile ẹjọ kekere se.

Amọ, ile isẹ ọlọpaa ni Naijiria ti ni iwadii si n lọ lọwọ lori ẹsun ifipabanilopọ naa, pe awọn ko i tii pari isẹ lori rẹ.

Busola Dakolo, ẹjọ́ ti kọjá odún mẹ́fà - Ileẹjọ

Ile ẹjọ giga ni ilu Abuja ti fi ọwọ osi da ẹjọ ti ilumọọka ayaworan, Busola Fatoyinbo pe mọ pasitọ agba ile ijọsin Commonwealth of Zion Assembly (COZA).

Dakolo fi ẹsun ifapabanilopọ kan Fatoyinbo ni ogun ọdun sẹyin.

Idajọ ile ẹjọ waye lẹyin ti Fatoyinbo gbe ẹjọ kotẹmilọrun lati fi ẹsun kan Busola wi pe o ba orukọ oun je, ti o si puro mo oun lori esun ti busola fi kan oun.

Fatoyinbo ni lati ibẹrẹ ni Busola ti n ba oun lorukọ jẹ, ti o si ba awọn oniroyin sọrọ lasiko ile isẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun naa.

Adajọ Oathman Musa ni ẹsun ti Busola pe mọ Fatoyinbo ko lẹsẹ n le, bakan naa ni wọn fi akoko ile ẹjọ sere.