‘Fún ìgbá díẹ̀ ni, Ibadan ko dòtí’
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ibadan: awon araalu figbe bonu pe ilu doti

Ijọba ipinle Ibadan ti ni ipinlẹ Oyo to doti ko sẹyin bi ijọba se yan adari tuntun fun ileeṣẹ to mojuto imọtoto ilu.

Awọn ara ilu pariwo si ta lori bi gbogbo agbeegbe ilu Ibadan se doti, eleyii to lewu fun ilera ara wọn.

Kọmisana fun ọrọ ayika ni ipinlẹ Ọyọ, Asofin Kehinde Ayọọla ṣalaye wi pe o ni bo se jẹ lori igboro ilu Ibadan to dọti

Ayọọla ni laipẹ yii ni gomina ipinlẹ Ọyọ,Ṣeyi Makinde gba iṣẹ lọwọ ileeṣẹ aladani to n ṣiṣẹ kolẹkodọti tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, ti o si yan adari tuntun fun ileeṣẹ to mojuto imọtoto ilu.

Kọmisana naa fi kun pe lọgan ti adari tuntun lẹka ileeṣẹ to n ṣe imọtoto ilu, ba wọle s'ẹnu iṣẹ, ni ayipada yoo deba imọtoto ipinlẹ Oyo