PDP: Ọjọ́rú la máa mọ̀ bóyá Jonathan ṣelòdì sí PDP ní ìdìbò Bayelsa

Aworan Aarẹ ana, Jonathan ati ami idamọ ẹgbẹ oṣelu APC Image copyright Alamy
Àkọlé àwòrán Àwọn adarí ẹgbẹ́ òsèlú APC se àbẹ̀wò sí Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí, Goodluck Jonathan ní ìdìbò sípò gómìnà ní Bayelsa.

Ẹgbẹ oselu PDP ti ni ibi ipade awọn igbimọ amusẹya ẹgbẹ oṣelu PDP ti yoo waye lọla ni awọn yoo ti se agbeyẹwo bi eto idibo ṣe lọ ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.

Akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ologbondiyan lo sọ ọrọ yii lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn adari ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Bayelsa ṣe ṣe abẹwo si Aarẹ tẹlẹri, Goodluck Jonathan lẹyin idibo sipo gomina to waye ni Bayelsa.

Minisita abẹle fun ọrọ to jẹmọ epo bẹntiroolu, Oloye Timipre Sylva ati Gomina ti wọn dibo yan ni ipinlẹ Bayelsa, David Lyon pẹlu awọn to lo ṣe abẹwo naa.

Ologbondiyan ni nibi ipade Ajọ amuṣẹya naa ni awọn yoo ti yanayan ipa ti ẹgbẹ oṣelu PDP ko ninu idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Bayelsa ati Kogi.

O ni awọn yoo ṣe agbeyẹwo abẹwo ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣe si Jonathan ati igbesẹ ti awọn yoo gbe lori rẹ.

Ẹgbẹ oṣelu PDP kuna lati kẹsẹjari ninu idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Bayelsa, lẹyin ogun ọdun ti wọn ti n ṣe ijọba ipinlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKogi vs Bayelsa: Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀