Heatwave: Njẹ́ ó mọ àwọn àìsàn aṣeku pani to rọ mọ ooru?

fan and co
Àkọlé àwòrán Heatwave: Njẹ́ ó mọ àwọn àìsàn aṣeku pani to rọ mọ ooru

Laípẹ yìí ní àjọ ilẹ̀ òkèèrè kan ti wọ́n n pè ni Sustainable Energy for all (SEA) gbé abájade ìwádìí rẹ̀ kan jáde pé mílíọnù ọmọ Naijiria ni ó wà nínú ewu atẹgun òòrun èyi to sì le di ìgbọ́na ní Naijiria.

Bákan náà ni àjọ to ń rí sí ojú ọjọ ni ní Naijiria náà ti kéde pé ooru to buru ju ti àtẹyin wá lọ yóò ja ní orílẹ̀-èdè Naijiria, to fi mọ àwọn agbègbè ti o maa n tutu tẹ́lẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bi ajọ ilẹ̀ òkèèrè náà ṣe sọ, pé afẹ́fẹ̀ òòrun yìí yóò pọ̀jù ni orílẹ̀-èdè Naijiria, Angola, Benin, Burkina Faso, Djibouti, Guinea-Bissau, Liberia, Malawi, Mozambque, South Sudan àti Togo.

Wọn ni níbi wọnyii ni yóò ti ni ipalára ó kéré tan ìdá ọgọ́ta nínú ọgọrun un àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè náà ló wà nínú ewu afẹ́fẹ́ gbigbona.

Ìwádìí náà fi kun un pé, yóò buru jáì nítori pé, ìdá ogun kò ni ànfani si ina láti lo amúle tutu kankan, ti wọn sì ń gbé láàrin ọ̀pọ̀ èrò pàápàá jùlọ láwọn ìlú ǹla.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionUI graduation: Fasiti Ibadan ló fún mi ni ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí mo fi kàwé síi- Habibat

Wo diẹ ninu Ewu àti Aisan to rọ mọ afẹ́fẹ́ òòru náà:

Gẹ́gẹ́ bi Dokita Yemisi Adeyeye, tó jẹ onímọ iṣẹ̀gun òyinbo to ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ṣe ṣalaye, o ni aisan pọ to n tẹle ooru àmújù.

Dokita yii to tun jẹ adári àgbà Life Fount Hospital ati Foundation ní ìlú Ilorin tii ṣe olú ilú ìpínlẹ̀ Kwara ṣàlàyé pé, oníruuru àìsàn lo n bá afẹ́fẹ́ oorun yìí rìn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele

Dokita Adeyeye ni ti òòru yìí ba pọ jù, o le la ikú lọ, nítori pe ti ooru yìí ba ti pọ ju, a maa rẹ ènìyàn sínu, ara eniyan a maa hu, ti o si lé mu ki èniyan ma mọ ǹkan to n ṣe mọ.

Ati pe, nígbà míran o le yi si aarun rọpa rọsẹ̀ (heatstroke)

Yatọ si èyi, ooyi le maa kọ èni náà ti ooru ba ti pọju, ti ẹni náà o ba wa ri ìrànwọ́ lásiko, lé mu ki èniyan sọ iye wọ́n nu

O le fu ki omi ara gbé, lko si ni jẹ ki èniyan le pa ọkan pọ soju kan nítori pe ọkan iru ẹni bẹẹ ko ni papọ soju kan

Iru ẹni ti nkan bayii ba ṣẹlẹ si gbọdọ lo si ilé ìwosan lásìkò lẹ́yin ti wọn ba ti rọ omi lee lori tan

Ọ̀nà láti dènà ooru gbígbóná:

Dokita Adeyeye sọpé O ṣe pàtàki láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ ti yóò dẹ́kun kí ènìyàn lùgbadi awọn àìsan to rọ mọ ooru gbígbọnà

Ní akọkọ ti ó bá sàkíyesí pé ooru mú, wá ọ̀na láti kúro ni irú àyiká bẹ́ẹ̀ nítori kò si ǹkan ìtìjú nibẹ̀.

O ṣe pàtàkì láti maa gbe àgé omí rẹ káàkiri ni ìgbà gbogbo nítori pé, omi mímú lóòrekore a maa mú ipa rẹ dínku.

Olúkúlùkù gbọ́dọ ri dáju pé àwọn yàrá àwọn ni fèrèsé ti afẹ́fẹ́ le gba wọle dáada láti dẹ́kun ooru

Nígbà ti ooru ba pọju ó ṣe pataki láti wa baluwẹ la'ti bu omi tutu lura tàbi ki a fi àsọ si ọmi lati gbe le ara kí o le tutù.