Lagos Prince: Ilé ẹjọ́ ṣèdájọ́ ikú f'ọmọ Ọba ìlú Eko tẹ́lẹ̀ lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn

Adewale Oyekan ati Lateef Balogun Image copyright @TeamAfroNaija
Àkọlé àwòrán Wọn ni Adewale bẹ Lateef lọwẹ lati gba ẹmi arabirin Sikirat to si fun ni ẹgbẹrun un mẹfa naira owo iṣẹ

Ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Eko ti ṣe idajọ iku fun Adewale Oyekan, to jẹ ọmọ ọba ilu Eko tẹlẹ, Ọba Adeyinka Oyekan.

Ile ẹjọ naa ni ki wọn yẹgi fun Adewale titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ lẹyin ti wọn ni o jẹbi ṣiṣekupa ọga rẹ, Alhaja Sikirat Ekun.

Adewale ni wọn ni o jẹbi ẹsun ipaniyan pẹlu ẹnikeji rẹ, Lateef Balogun to jẹ oṣiṣṣẹ ninu ile arabinrin ọhun.

Iroyin ni Adewale bẹ Lateef lọwẹ lati gba ẹmi arabirin Sikirat to si fun un ni ẹgbẹrun mẹfa naira owo iṣẹ.

Lẹyin eyi ni wọn ju oku arabinrin ọmọ ọdun mejilelọgọta naa sinu kanga ti jinjin rẹ to iwọn ẹsẹ bata ẹgbẹrun kan, ti wọn si gbe ẹrọ amunawa lee lori.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa

Agbẹjọro fun ijọba, Akin George ni lẹyin oṣu meji ni wọn to ri oku obinrin naa nibi ti wọn sọ ọ si ninu kanga ọhun.

Awọn ọdaran naa ti wa latimọle fun ọdun meje lati igba ti ọwọ ofin ti ti tẹ wọn ki wọn to da ẹjọ wọn bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIná PHCN tó dé lójijì ṣàkóbá ńlá ní Ibadan

Ni igba to n ka idajọ rẹ, Adajọ Raliatu Adebiyi ni iwadii fihan pe otitọ ni pe awọn ọdaran naa lo ṣekupa oloogbe Sikirat, lẹyin naa lo ni ki wọn lọ yẹgi fun wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'