Sotitobire church: Àwọn ọ̀dọ́ ilu dáná sun ilé ìjọsìn Sọtitobirẹ nílú Akure

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSotitobire church: Àwọn ọ̀dọ́ ilu dáná sun ilé ìjọsìn

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe ayederu iroyin ni pe wọn ba oku ọmọ kekere ninu ile ijọsin Sọtitobirẹ Miracle Centre, nilu Akurẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Ọgbẹni Femi Joseph sọ fun BBC Yoruba pe awọn to dana sun ile ijọsin naa pa ọkan lara awọn ọlọpaa to lọ dena wahala.

Iṣẹlẹ yi waye lasiko ti wọn n dana sun ile ijọsin naa ni owurọ Ọjọru.

Lori iroyin pe ọlọpaa yinbọn pa ẹnikan nibi iṣẹlẹ naa, Ọgbẹni Joseph sọ pe oun ko le sọ pe nkan bẹ ẹ ṣẹlẹ.

"Mi o gbọ pe ọlọpaa pa ẹnikẹni nibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn nkan ti mo le sọ ni pe iwa ọdaran ni didana sun ile onile."

"Ọlọpaa le lo ọnakọna, to fi mọ yinyin ibọn mọ afurasi ti ọwọ ba tẹ pe o n dana sun ile onile, ni ẹsẹ, ti iru afurasi bẹ ẹ ba n saalọ.

Ti ibọn ba ba a ni ẹsẹ, to ba gba ibẹ ku, ko buru."

Ṣaaju ni iroyin kan gbode kan lowurọ yii pe wọn ri oku ọmọdekunrin Gold to dawati nile ijọsin Sotitobire nilu Akure, ni awọn ọlọpaa lọ si ile ijọsin ọhun.

Image copyright @horpizzle
Àkọlé àwòrán Bi awọn kan ṣe n sọ ina sinu ile ijọsin naa ni awọn mii n jo ọkọ̀

Ṣugbọn ọpọ ero to wa nibẹ ko jẹ ki awọn ọlọpaa ṣe iṣẹ wọn, eyii lo mu ki wọn yin tajutaju si awọn eeyan ọhun.

Ni ọrọ ba di boo lọ ko yago fun mi ni eyi ti wọn ni ibọn ti ba ọdọkunrin meji.

Lẹyin naa ni awọn ọdọ ilu dana sun ile ijọsin naa.

Akọroyin BBC to wa nilu Akure nigba ti iṣẹlẹ ọhun waye jabọ pe, oun ko tii le fidi rẹ mulẹ pe wọn ri oku ọmọ naa nile ijọsin ọhun tabi bẹẹ kọ ṣugbọn wọn ko gbe oku ọmọ kankan sita ṣaaju didan sun ile ijọsin naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Buns ni ọmọ mi jẹ tán ní ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá di àwátì'

O ni awọn eeyan kan farapa ninu rogbodiyan naa, ti wọn si ti gbe wón lọ sile iwosan fun itọju ẹsẹ ti wọn ti gba ọgbẹ.

Ṣaaju ni awọn ẹgbẹ obinrin ni ipinlẹ Ondo ti ṣe iwọde pe ki Gomina Akeredolu gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ yii Àwọn abiyamọ figbe ta lórí ọmọ ọdún kan ti wọn wá nílé ìjọsìn l'Akure

Bi awọn kan ti n bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu awọn ọdọ agbegbe to dana sun ile ijọsin pe ko yẹ ki wọn gbe igbesẹ yii ni awọn miran ni awọn agb pe ijọba yoo ṣe ohun to kan bayii.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Akure Kidnap: Wọ́n ti dáná sun ilé ìjọsìn Sọtitobirẹ nílú Akure

Iroyin to n tẹwa lọwọ ni yajoyajo sọ pe awọn eeyan ti dana sun ile ijọsin Sọtitobirẹ Miracle Centre nilu Akure ni ipinlẹ Ondo.

Bi awọn kan ṣe n sọ ina sinu ile ijọsin naa ni awọn mii n jo ọkọ̀ ti ọrọ di boolọ koo yago fun mi"Àwọn tó jí ọmọ mi gbé nílé ìjọsìn ní ń kò gbọdọ̀ wa tàbí kí ẹ̀mí mi lọ si".

Eyi ko ṣeyin iṣẹlẹ to waye nile ijọsin ọhun loṣu to kọja lataari bi ọmọdekunrin jojolọ kan ṣe di awati nibẹMissing Child: Òbí àti asọ́nà ṣọ́ọ̀ṣì 14, lọ́ búra nì'dí imọlẹ̀ l'Akure .

Image copyright @OlugbengaAyo
Àkọlé àwòrán Oṣu to kọja ni ọmọdekunrin jojolo kan di awati nile ijọsin ọhun

Lẹyin naa ni iya ọmọ ọhun ke gbajari sita, ti awọn agbofinro si pe oluṣọagutan ijọ naa, woli Alfa Babatunde, fun ifọrọwanilẹnuwo.

Ẹ wo awọn aworan diẹ lara awọn ohun to ṣelẹ nibẹ.

Image copyright @YemieFash

Bi awon kan ṣe n pariwo pe wọn ri oku ọmọ naa nile ijọsin yii ni awọn miran ni pe irọ ni. BBC ko tii le fidi ohun to n ṣẹlẹ ni pato mulẹ.

Sugbọn, ohun ti a ri dimu ni koko ni pe, wọn ti dana sun ile ijọsin naa bayii.

BBC Yoruba yoo maa mu bi ohun gbogbo ba ṣe n lọ wa si oju opo yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOluwo Divorce: ko si ẹni ti kò mọ pé ọmọ ilẹ̀ òkèrè ni mó fi ṣe aya