America bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣọ́ Naijiria lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ tóri ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn

Mike Pompeo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Amẹrika ti fi orukọ Naijira sara awọn orilẹede to ni ko faaye gba awọn eeyan lati ṣe ẹsin to wu wọn.

Akọwe ijọba orilẹede ọhun, Mike Pompeo sọ pe Naijiria ti dara pọ mọ awọn orilẹede bii China, Eritrea, Iran, North Korea, Pakistan, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Igbesẹ yii wa latari bi wọn ṣe ni Naijiria kii bikita fun awọn ti wọn ba n dojukọ iṣoro ija ẹsin.

Ọgbẹni Pompeo ṣalaye pe oreọfẹ lati ṣe ẹsin to ba wu ẹni jẹ orilẹede Amẹrika logun.

Ati pe ko ni ṣatilẹhin fun orilẹ-ede to ba n fun awọn eeyan lọrun latari ọrọ ẹsin.

O ni orilẹ-ede Amẹrika ko ni dakẹ lori ọrọ awọn orilẹede to ba n fi ẹtọ awọn eeyan dun wọn nitori ẹsin wọn.

Àkọlé fídíò,

Ǹkan tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn mí kí n tó bẹ̀rẹ̀ orin ìfèdèfọ̀ rèé- Testimony Jaga