Sambo Dasuki: Ìdí tí ìjọba fi tú Dasuki àti Sowore sílẹ̀ rèé - Malami

Sambo Dasuki

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọjọ Iṣẹgun ni ijọba apapọ tu Dasuki silẹ, lẹyin to ti lo ọdun mẹrin o le diẹ ninu ẹwọn

Agbẹjọrò Sambo Dasuki, Ahmed Raji si ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, wọ́n ti tú onibara oun silẹ̀ èyí ti ó jẹ́ Dasuki.

Adajọ agba lorilẹ-ede Naijira, Abubakar Malami ti sọ pe aanu ọmọniyan ati ibọwọ fun ofin lo mu ijọba tu Sambo Dasuki ati Omoyele Sowore silẹ.

Abubakar Malami sọ fun BBC pe, ijọba Naijiria rii pe o to akoko lati tẹlẹ aṣẹ ile ẹjọ lori ọrọ itusilẹ Dasuki ati Sowore ni.

Adajọ agba naa ni kii ṣe nitori akitiyan ilẹ Amẹrika ni wọn ṣe tu wọn silẹ, ati pe kii ṣe nitori pe Sowore jẹ ọmọ orilẹ-ede ọhun.

Ṣaaju lọjọ Iṣẹgun ni ijọba apapọ tu Dasuki silẹ, lẹyin to ti lo ọdun mẹrin o le diẹ ninu ẹwọn latari pe o jẹbi ẹsun kikowo ohun ija ogun sapo.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Jesu ni ọjọ́ ọ̀la àti ibi ìyanu mi- Jaga

O ni "Ko si idi miran ti a fi tu wọn silẹ bi koṣe lati tẹlẹ ti aṣẹ ile ẹjọ ti kọkọ pa."

Malami tẹsiwaju pe wọn tu wọn silẹ nitori aanu ọmọniyan, bo tilẹ jẹ pe ijọba si le pẹ igbẹjọ tako idajọ to ni ki wọn tu wọn silẹ.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Ẹni ti ọdun ba ti bá láyé yẹ kó dúpẹ́

O ni ijọba ko tii gba lẹta lati ilẹ Amẹrika lori ọrọ naa, nitori naa, ahesọ lasan ni pe ifunlọrun ilẹ Amẹrika lo fa ṣababi itusilẹ wọn.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Sambo Dasuki: Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún mẹ́rin, adarí ètò aàbò Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Dasuki, yóò sun yàrá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, prnigeria

Àkọlé àwòrán,

Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún mẹ́rin, adarí ètò aàbò Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Dasuki yóò sun yàrá rẹ̀

Minisita feto aṣa nigba kan ri ni Naijiria, Femi Fani Kayode sọ pe oun mọ eeyan mẹrin to ja fitafita ki ijọba fi tu Sambo Dasuki ati Omoyele Sowore silẹ.

O fi ọrọ yi sita loju opo Twitter rẹ lẹyin ti Sambo Dasuki, Olubadamọran pàtàkì lóri ààbo (NSA) tẹ́lẹ̀rí ati Omoyele Sowore to jẹ oludije ninu idibo aarẹ to kọja gba itusilẹ.

Fani Kayode darukọ Abba Kyari, olori oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ, Abubakar Malami, Minisita feto idajọ, Hadi Sirika to jẹ Minisita feto irinajo ọkọ ofurufu ati Kayode Fayemi, Gomina Ekiti.

O ni awọn wọn yi jẹ ogun agbongbo awọn to fẹ itẹsiwaju ninu ijọba Buhari.

Bakan naa ni o sọ pe ọjọ manigbagbe ni aisun ọjọ Keresi yi jẹ nitori ''ọjọ kan yi ni awọn kan gbiyanju lati gbẹmi aarẹ ana, Goodluck Jonathan ti wọn si tun tu ọrẹ mi Sambo Dasuki silẹ lẹyin atimọle ọdun mẹrin''

Ẹwẹ, aworan bi Sambo Dasuki ti ṣe darapọ mọ awọn mọlẹbi rẹ nile rẹ to wa ni ilu Abuja ti n gba ori ayelujara.

Ni nnkan bi aago mẹsan an alẹ ọjọ Iṣẹgun lo gunlẹ si ile rẹ tawọn ẹbi ati ọrẹ si fi tijo tayo pade rẹ.

Oríṣun àwòrán, SaharaReporters

Ki lawọn eeyann sọ nipa itusilẹ Dasuki ati Sowore

Ariwisi ọtọọtọ ni itusilẹ awọn mejeeji yi mu wa lori opo ayelujara ṣugbọn eyi to fẹ pọju lọ ni ti ayọ ati idunnu pe wọn gba ominira.

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

Nínú àtẹjade to fọ́wọ́ sí fun ara rẹ̀, Malami ni ìgbésẹ̀ náà kò ṣẹ̀yìn ìgbẹ́jọ ilé ẹjọ to ni ki o gba òmìnìra

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Bi ọrọ naa ti ṣe ṣẹlẹ

Lọjọ Iṣẹgun ni olubadamọran pàtàkì lóri ààbo (NSA) tẹ́lẹ̀rí Col. Sambo Dasuki ti tun pada gba òmìnira lẹ́yin to lo ọdun mẹ́rin ati ìgbà díẹ̀ n àhámọ àwọn àjọ ọtẹlẹ̀múyẹ Naijiria.

Wọ́n tú Dasuki sílẹ̀ lọ́gbà àwọn àjọ DSS l'Abuja lẹ́yìn ti àdájọ àgbà Naijiria Abubakar Malami pàṣẹ pé ki àjọ náà tẹ̀lẹ àṣẹ ilé ẹjọ to ni ki wan gba ìtúsílẹ̀.

Àkọlé fídíò,

Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Agbẹjọrò Sambo Dasuki Ahmed Raji si ti fio ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, wọ́n ti tú onibara oun silẹ̀ èyí ti ó jẹ́ Dasuki.

O dúpẹ lọ́wọ́ adajọ àgbà fun àṣẹ láti tú oníbara òun sílẹ̀ ni ìbámu pẹ̀lu gbogbo ìdájọ àwọn ilé ẹjọ ti ọ̀rọ̀ náà ti dé.