Yollywood: E wo bí àwón òṣèré tíátà Yoruba ṣe ṣàjọyọ̀ ọdún Kérésìmesì

Toyin Abraham, Funke Akindele ati Bimbo Oshin

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán,

Bi awọn oṣere tiata Yoruba ṣe ṣajọyọ ọdun Keresi ṣọtọtọ

Keresimesi ọdun yii o yẹ, o dun, o si larinrin pẹlu.

Oriṣirṣi ọna ni awọn eeyan fi ṣe Keresi ọdun yii, bi awọn kan ṣe n jẹ ti wọn si n mu, lawọn mii n ṣe iranlọwọ fun awọn alaini.

Awọn oṣere tiata Yoruba naa ko gbẹyin ni bi wọn ṣe ṣe ọdun naa loriṣiriṣi ọna.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Ẹni ti ọdun ba ti bá láyé yẹ kó dúpẹ́

1. Funke Akindele

Ọna ti Funke Akindele fi ṣe ọdun Keresi ni lati ṣe awọn ololufẹ rẹ loore.

Gẹgẹ bi ọrọ to fi lede loju opo Instagram rẹ, Funke yoo mu tọkọtaya mẹta lọ jẹ igbadun eto "Dubai Shopping Festival" lorilẹ-ede United Arab Emirates.

Bo tilẹ jẹ pe a ko lee fidi rẹ mulẹ pe Funke ni yoo san owo irinajo naa, ṣugbọn eyi jẹ anfani nla fun awọn ololufe rẹ lati lati rinrin ajo lo oke okun lai san kọbọ.

Funke gba awọn oloufẹ rẹ lamọran lati ma na gbogbo owo tan lasiko ọdun, nitori oṣu kinnin ọdun 2020 n kan lẹkun.

2. Faithia Williams

Ni ṣe lo dabi ẹni pe ọwọ jẹlẹnkẹ ni ọdun ọhun ba de fun Faithia Williams.

Oun naa ki awọn ololufẹ rẹ kaakiri orilẹ-ede agbaye loju opo Instagram rẹ.

O ni akoko ọdun Keresi jẹ akoko lati fi ifẹ han si awọn elomiran, o si ran awọn tirẹ leti lati fọwọ tọ ọkan awọn elomiran nipa ṣiṣe rere lasiko ọdun ọhun.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Jesu ni ọjọ́ ọ̀la àti ibi ìyanu mi- Jaga

3. Toyin Abraham

Ara ọtọ ni ayẹyẹ ọdun keresi ọdun 2019 gba yọ lati ọdọ Toyin Abraham.

Fidio aladun kan bayii lo fi ki awọn tirẹ ku ọdun Keresi.

Oun pẹlu idile rẹ lo wa ninu fidio ọhun.

Àkọlé fídíò,

Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide

4. Iyabo Ojo

Iyabo Ojo naa fi fidio lede loju opo Instagram rẹ lati ki awọn ololufẹ rẹ ku ọdun Keresimesi.

Ninu fidio ọhun ni Iyabo ti fi oju awọn ọmọ rẹ lede ninu yara, ti oju wọn si da bi oju Baba Keresi.

Lẹyin naa lo kọ akọle kan to sọ pe "lati ọdọ wa si yin, a ki yin ku ọdun Keresimesi."

Àkọlé fídíò,

Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?

5. Bimbo Oshin

Bimbo Oshin naa ko gbẹyin lara awọn gbajugabja oṣere tiata Yoruba to n ki awọn tirẹ ku ọdun Keresi.

O ni "Mo ki ẹyin ololufẹ, ọrẹ ati ẹbi mi ku ọdun Keresimesi."

Bimbo pari ọrọ pe "A o pade lọdun 2020 ni orukọ Jesu. Amin."

Àkọlé fídíò,

Ǹkan tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn mí kí n tó bẹ̀rẹ̀ orin ìfèdèfọ̀ rèé- Testimony Jaga