Sowore: Garba Shehu ni ijọba Buhari ko tii fi akọroyin kankan satimọle lati ọdun 2015

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Garba Shehu ni ijọba Buhari ko tii fi akọroyin kankan satimọle lati ọdun 2015

Olubadamọran pataki fun aarẹ Muhammadu Buhari lori iroyin, Garba Shehu ti sọ pe ijọba Buhari ki n ṣe ijọba to n ti awọn akọroyin mọle.

Garba lo sọ ọrọ yii loju opo Facebook rẹ lọjọ ọdun Keresimesi latari bi awọn ile iroyin kan lagbaye ṣe n pe Omoyele Sowore ni akọroyin.

Àkọlé fídíò,

Ǹkan tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn mí kí n tó bẹ̀rẹ̀ orin ìfèdèfọ̀ rèé- Testimony Jaga

O ni ijọba Buhari ko fi panpẹ ofin mu Sowore nitori o jẹ akọroyin, ṣugbọn nitori pe o gbe igbesẹ lati doju ijọba bolẹ.

Ninu atẹjade naa, Shehu sọ pe "Lati igba ti aarẹ Buhari ti gori aleefa lọdun 2015, ko tii fi akọroyin kankan satimọle."

O tẹ siwaju pe "Ijọba yii ko tii gbe agadagodo sẹnu ile iroyin kankan, bẹẹ ni ko gbẹse le iwe iroyin kankan."

Àkọlé fídíò,

Christmas: Ẹni ti ọdun ba ti bá láyé yẹ kó dúpẹ́

Shehu ni Sowore lo ipo rẹ gẹgẹ bi gbajumọ lati idoju ijọba bolẹ lori ẹrọ amohunmaworan ati ninu iwe iroyin rẹ lori itakun agbaye.

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

O sọ pe ko si ijọba kan to nifẹ ara ilu lọkan ti yoo laju rẹ silẹ ki eeyan kan wa da oju ijọba rẹ bolẹ.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Jesu ni ọjọ́ ọ̀la àti ibi ìyanu mi- Jaga