Boxing Day: Kíni ìdí tí wọ́n fi ń pe ọjọ́ kejì ọdún Kérésì ní Boxing Day?

Boxing Day

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ninu iwe itan, awọn ile ijọsin naa kopa ninu ṣiṣagbekale ọjọ 'Boxing Day'

Itan 'Boxing Day' yii bẹrẹ lakoko ti Ọọbabirin Victoria wa lori aleefa niwọn ọdun 1800.

Boxing Day ko ni nnkankan ṣe pẹlu ẹṣẹ kíkàn gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe lero.

Orisun orukọ naa bẹrẹ pẹlu bi awọn ọlọla ṣe maa n di ẹbun sinu apoti, ti wọn si maa n pin fun awọn alaini lọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Boxing Day ko ni nnkan ṣe pẹlu ẹṣẹ kíkàn

Ọjọ ọhun jẹ ọjọ ti awọn ẹru kii ṣe iṣẹ kankan, ti awọn olowo wọn si maa n fun wọn ni ẹbun ọdun Keresi ninu apoti.

Àkọlé fídíò,

Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Awọn ẹbun ọhun ni awọn ẹru naa maa n gbe lọ fun awọn ara ile wọn ki wọn fi ṣafihan bi awọn olowo awọn ṣe mọ riri iṣẹ ti wọn ṣe lodindin ọdun kan to.

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

'Boxing Day' tun jẹ ọjọ ti awọn orilẹ-ede kan bii Hungary, Germany, Poland ati Netherlands maa n ṣe ajọyọ ọjọ to tẹle ọjọ ọdun Keresimesi.

Àkọlé fídíò,

Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide

Ipa ti ijọ ko

Ninu iwe itan, awọn ile ijọsin naa kopa ninu ṣiṣagbekale ọjọ 'Boxing Day'to wa fun pinpin ẹbun fi mọ riri ara ẹni.

Lẹyin ti wọn ba ti gba owo ọrẹ lọwọ awọn ijọ laarin ọdun, wọn maa n ko owo naa sinu apoti, wọn a wa ṣi apoti owo ọrẹ yii lọjọ keji ọdun Keresi, ti wọn a si pin owo inu rẹ fun awọn talaka.

Àkọlé fídíò,

Mo n wa'yawo - Falz

Ọjọ wo ni ọjọ' Boxing Day'?

Boxing Day jẹ ọjọ keji, ọdun Keresimesi, o si maa n bọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn, ninu oṣu Kejila ọdun.

Àkọlé fídíò,

Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?

Ọjọ ọhun tun jẹ ọjọ isinmi lorilẹ-ede Naijiria ati ni awọn orilẹ-ede miran lagbaye.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Ẹni ti ọdun ba ti bá láyé yẹ kó dúpẹ́

Lorilẹ-ede wa nibi, ọjọ yii jẹ ọjọ faaji ati ọjọ igablejo loriṣiriṣi fun ọpọ eeyan.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Jesu ni ọjọ́ ọ̀la àti ibi ìyanu mi- Jaga

Ọjọ ọhun tun jẹ ọjọ ti awọn eeyan ma jẹ ajẹyo ati ajẹṣẹku ounjẹ ti wọn se lasiko ọdun.

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ