Kano Marwa: Awakọ̀ kẹ̀kẹ́ Maruwa tó bá gbé okùnrin àti obìnrin ní Kano yóò jẹ palamba ìyà- Hisbah

Kẹkẹ Maruwa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Hisbah ni ofin naa ti wa lati ọdun 2005, ṣugbọn wọn ṣẹṣẹ fẹ bẹrẹ si ni mulo ni

Ijọba ipinlẹ Kano ti sọ pe, o ti di eewọ fun awakọ keke Maruwa lati gbe okunrin ati obinrin papọ nipinlẹ ọhun.

Ajọ ọlọpaa Sharia ipinlẹ naa, Hisbah sọ pe, lati ọjọ keji oṣu, Kinni ọdun 2020, ẹnikẹni ti wọn ba gba mu pe o ru ofin naa yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

Adari ajọ naa, Sheik Harun Ibn-Sina fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC.

O ni, ijiya fun ẹni to ba tapa si ofin naa ni pe wọn yoo gbẹsẹ le kẹkẹ rẹ fun oṣu mẹfa, tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun marun un naira ati bulala mẹwaa.

Àkọlé fídíò,

Christmas: Ẹni ti ọdun ba ti bá láyé yẹ kó dúpẹ́

Ibn-Sina ṣalaye pe "Ofin yii ti wa lati ọdun 2005, ṣugbọn a ṣẹṣẹ fẹ bẹrẹ si ni muu lo ni, ki a le fọ ipinlẹ wa mọ."

O ni lati akoko yii di ipari ọdun, awakọ maruwa to ba gbe obinrin ati okunrin papọ yoo ni lati ja ero kan silẹ.

Ṣugbọn lati ọjọ keji oṣu, Kinni ọdun 2020 ni ijiya ni pẹrẹu yoo bẹrẹ fun awọn to ba tapa sofin naa.

Àkọlé fídíò,

Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide

Ibn-Sina ni awọn ẹṣọ ajọ ọhun ti gunlẹ si gbogbo ijọba ibilẹ mẹrinlelogoji to wa nipinlẹ Kano lati fẹsẹ ofin ọhun mulẹ.

Àkọlé fídíò,

Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

O ni tọkọtaya lee wọ keke kan naa papọ ti wọn ba lee bura pe awọn mejeji ti gbera wọn niyawo.

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀