Premier League: Southampton dáná sun Stamford Bridge pẹ̀lú àmì ayò 2-0

Nathan Redmond Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Southampton dáná sun Stamford Bridge pẹ̀lú àmì ayò 2-0

Ikọ Southampton fẹyin Chelsea gbolẹ nile wọn ninu idije Premier League to waye lonii.

Iya ti Chelsea jẹ lonii ko ṣẹyin akitiyan Micheal Obafemi ati Nathan Redmond ninu ifẹsẹwọnsẹ naa to waye ni papa iṣere Stamford Bridge.

Micheal Obafemi lo kọkọ dana sile Chelsea ninu abala kini ifẹsẹwọnsẹ naa.

Ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni Redmond naa sọ goolu tirẹ sinu awọn.

Bo tilẹ jẹ pe Chelsea ṣe bi okunrin, to si gbiyanju lati ri ẹyin awọn Southampton, ṣugbọn ko lee ta putu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionChristmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Ni bayii, ikọ Chelsea ti wa ni ipo kẹrin lori tabili lẹyin to n tẹle Manchester City lẹyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPolice Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide