Kano witches: Wo ìdí tí ìjọba Kano ṣe ń tilẹ̀kùn ṣọ́ọ̀bù àwọn babaláwo ìpinlẹ̀ náà

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Olugbe ilu Kano kan sọ fun BBC bi oun ṣe ko sọwọ awọn oni gbajuẹ naa nigba ti oun ṣe aisan

Ọga agba ajọ eleti gbaroye ati igbogun ti iwa ibajẹ ipinlẹ Kano, Muhiyi Magaji ti sọ fun BBC pe, idi ti ajọ ọhun ṣe n ti ilẹkun ṣọọbu awọn babalawo ati ariran ni ipinlẹ naa ni pe wọn n lu awọn eeyan ni jibiti.

Gẹgẹ bi ọrọ to sọ, wọn ti fi panpẹ ofin mu awọn ayederu babalawo mẹrin, wọn o si tẹsiwaju titi di igba ti awọn ara ilu yoo dekun ati maa fẹjọ wọn sun.

Magaji ṣalaye pe "A fofin mu okunrin kan ni ijọba ibilẹ Albasu to n pe ara rẹ ni Ọba awọn oṣo, to si jẹwọ fun wa pe ofege ni oun."

O ni ajọ naaa tun mu okunrin miran lagbegbe Makolo to pe ara rẹ ni alaga awọn babalawo ni gbogbo ipinlẹ Kano.

Image copyright Magaji
Àkọlé àwòrán Alaga ajọ amuni mu ẹgbo naa ati meji ninu awọn ti ọwọ tẹ

Olugbe ilu Kano kan, Sani Ibrahim sọ fun BBC pe oun ti ko sọwọ awọn gbajuẹ naa ri nigba ti oun n ṣe aisan.

Magaji sọ pe bi wọn ṣe n tu aṣiri awọn eeyan naa jẹ ara iṣe ajọ ọhun gẹgẹ bi eyii to n gbogunti iwa ibajẹ lawujọ

O ni oni jibiti ni awọn eeyan naa, wọn ko ni agbara kankan, ati pe ko yẹ ki awọn ara ilu maa bẹru wọn rara nitori o yẹ ki aye wọn dara ju bẹẹ lọ ka sọ pe lotọ ni wọn ni agbara.

Muhuyi kilọ fawọn eniyan pe ẹni to ba n wa ifa naa lo maa n ri ofo ati pe ẹni to ba n wa iwakuwa naa lo maa n ri irikuri.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAkure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá