Diya: A fẹ́ fí ọ̀nà òfin mú ọ̀rọ̀ yìí

Idile Diya

Oríṣun àwòrán, Mohamed Imran Noorgat/Facebook

Agbẹjọro idile oloogbe Pasitọ Gabriel Diya to ri sinu omi pẹlu ọmọ rẹ meji ti wọn si gba ibẹ jẹ Ọlọrun nipe lorilẹede Spain ti pe fun ṣiṣe iwadii finifini lori ọrọ naa.

Ẹni ọdun mejilelaadọta Diya ati ọmọbinrin rẹ ọmọ ọdun mẹsan to fi mọ ọmọkunrin ọmọ ọdun mrindinlogun ku lọjọ aisun ọdun keresimesi ninu omi adagun ni ile igbafẹ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Club La Costa World ni Fuengirola, Spain.

Ipe lati ṣewadii yii n wa lẹyin ti iyawo pasitọ naa, Olunbunmi diya figbe sita pe ejo lọwọ ninu ọrọ iku ọkọ atawọn ọmọ oun tori gbogbo wọn lo le luwẹ eyi to lodi si iroyin ti awọn kan n gbe kiri.

Ìyàwó Pásítọ̀ àti ìyá àwọn ọmọ méji tó ri sínú omi adagun kan nile igbafẹ́ lorilẹede Spain lásìkò tí wọ́n n lùwẹ̀ ní ọdun kérésìmesì ku ọ̀la, ní òun gbàgbọ́ pé ǹkankan ṣẹlẹ̀ nínú omi náà ni ó ṣe nira fún wọ́n láti luwẹ̀.

Olubunmi Diya ni ati ọkọ òun ẹni ọdun méjìléláàdọta, ọmọ ọkunrin wọn Praise Emmanuel to jẹ́ ọmọọdun mẹ́rindinlógún àti Comfort ọmọbìnrin wọn tó jẹ́ ọdun mẹ́sàn lo mọ bi èèyàn ṣe ń lúwẹ lòdì si àwọn ìròyìn kan to n lọ káàkiri.

Awọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú ni àìsùn ọjọ Kérésìmesì ni Club La Costa World ni Fuengirola ni ìhà Costa del sol, orilẹede Spain. Àlùfáà ìjọ Redeem àti ọmọ rẹ̀ méjì kú sílé ìgbafẹ́ kan lásìkò Kérésì

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Àkọlé fídíò,

Trump impeachment: Trump kò fìdí janlẹ̀ tán, àmọ́ níbo ni yóò jásì?

Ayaba Diya sọ nínú àtẹjade kan to fọ́wọ́si to si fi ṣọwọ si Sky News to si tun wa loju opo ijọ Redeem ti United Kingdom pe: "Mó ni ìgbàgbọ́ pé ǹkankan yíwọ́ nínú adágún omi náà ti o fi nira fún wọ́n láti wẹdo ní àsìkò náà."

Ṣùgbọ́n àwọn òṣìsẹ́ CLC World Resort and Hotels sọ pada láti fèsì pé: Àyẹwò fínífini ti àwọn ọlọpàá ṣe nítori ìṣẹ̀lẹ̀ ibi náà ti fi ìdí ẹ múlẹ̀ pé adágun omi náà ń ṣiṣẹ́ bo ṣe tọ àti bo ti yẹ, kò si sí ǹkankan to ṣẹlẹ lòdì.

Oríṣun àwòrán, @RCCGUK

Àkọlé àwòrán,

Mo funra si Swimming Pool ti ọkọ àti àwọn ọmọ mi rì sí- Olubunmi Diya

Agbẹnuso ilé iṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè náà ti fí ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ pé: "A n ṣe gbogbo ǹkan to wà ni ìkáwọ́ wa láti dúró ti Olubunmi Diya lórí ìṣẹ̀lẹ̀ aburu to ṣẹ̀lẹ̀ sí ìdílé rẹ́ ní Spain"