Fani-Kayode: Àjálù ni ìjọba Buhari jẹ́ fún Nàìjíríà

Fani-Kayode sọ pe ọrọ aje Naijiria ti dẹnu kọlẹ labẹ iṣejọba ààrẹ Buhari Image copyright facebook/Femi Fani-Kayode

Minisita fun eto irinna ofurufu tẹlẹ ri, Femi Fani-Kayode ti sọ pe arẹ Muhammadu Buhari ko ni ifẹ awọn ọmọ Naijiria lọkan.

Fani-kayode lọ sọ ọrọ yii lẹyin ti Aarẹ Buhari sọrọ lori bi ẹgbẹ agbesumọmi Islamic State IS, ṣe bẹ awọn kristẹni mẹwa lori ni ipinlẹ Bornu.

Ninu atẹjade to fi lede loju opo Twitter rẹ, o ni ogunlọgọ awọn Kristiẹni ni awọn agbesumọmi ti pa lorilẹ-ede yii lati nnkan bi ọdun marun un sẹyin, ti aarẹ ko si sọrọ nipa rẹ.

Fani-Kayode sọ pe oju aye lasan ni aarẹ n ṣe lẹyin to bu ẹnu atẹ lu iwa awọn agbesumọmi naa.

Minisita ana ọhun tun bu ẹnu atẹ lu Biṣọbu agba ti ijọ Canterbury pe, o n ṣegbe lẹyin aarẹ Buhari.

O ni Biṣọbu ọhun ko kọbi ara si iku awọn ọmọ lẹyin Kristi lorilẹ-ede yii.

Fani-Kayode ko dakẹ ọrọ naa ni bi o ṣe sọ pe ọrọ aje Naijiria ti dẹnu kọlẹ labẹ iṣejọba ààrẹ Buhari

Ọjọ keji ọdun Keresimesi ni ẹgbẹ IS fi fidio kan lede, ni ibi ti wọn ti yibọn pa ẹni kan ti wọn si bẹ awọn mẹwa toku lori ni Bornu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢé ẹ mọ bí ẹsẹ̀ yín ṣe ń gùn sí àti àkóbá tí bàtà ń ṣe fún yín?