Femi Falana: Ìjọba àpàpọ̀ gbọ́dọ̀ tọrọ ìdárìjì lọ́wọ́ Sowore àti Dasuki

Omoyele Sowore Image copyright Omoyele Sowore
Àkọlé àwòrán Minisita fún ètò ìdájọ́ ní Naijiria, Abubakar Malami ti ni òun káànú Ọmọyẹlẹ Sowore ni òun se fi sílẹ̀.

Agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana ti kọwe si Minisita fún ètò ìdájọ́ ní Naijiria, Abubakar Malami lati tọrọ aforiji lọ̀wọ oludasilẹ ile iṣẹ iroyin Sahara Reporters, Omoyele Sowore ti wọn ṣẹṣẹ fi silẹ lẹyin to ti wa ni atimọle Ajọ DSS fun ọpọlọpọ ọjọ.

Falana sọ eleyii lẹyin ti Malami fi lede wi pe oun kaanu Sowore to n pe fun atuntọ orilẹẹde Naijiria, RevolutionNow movement, ni oun se ni ki wọn fi silẹ ni ahamọ DSS to ti wa lati igba diẹ ati Sambo Dasuki to jẹ oluranlọwọ pataki fun eto abo Naijiria tẹlẹri, Sambo Dasuki ti wọn ṣẹṣẹ fi silẹ naa.

Malami ni awọn fi awọn mejeeji silẹ nitori awọn bọwọ fun ofin orilẹede Naijiria kii ṣe nitori pe awọn orilẹede to wa lokeere gbe ogun ti wọn.

Image copyright Omoyele Sowore
Àkọlé àwòrán Adajọ ti tu Soworẹ silẹ

Falana to jẹ agbẹjọrọ fun Sowore fi lẹta ṣọwọ si Malami nibi to ti sọ wi pe oun to ba ofin mu ni ki ijọba bọwọ fun idajọ ile ẹjọ to ni ki wọn fi Sowore silẹ, ti ijọba apapọ kọ jalẹ fun ọpọlọpọ igba.

O ni nitori ile ẹjọ ti gba beeli wọn, o yẹ ki ijọba bọwọ fun ofin Naijiria to wa ninu ẹka section 32 (6) ti iwe ofin ti ọdun , amọ wọn kọ lati bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria.

Nitori naa, Falana wa ke si Malami lati yara tọrọ aforiji lọwọ Soworẹ ati Dasuki nitori wọn tẹ oju ofin mọlẹ lori ọrọ wọn.

Bakan naa lo fi kun un wi pe Aarẹ orilẹede Naijiria ati awọn Gomina ipinlẹ lo ni aṣẹ labẹ ofin lati fi aanu da ẹnikẹni silẹ kuro ni atimọlẹ.