Sheu Sani kò lu jibiti, irọ́ ńlá ní wọ́n ń pa mọ́ọ- Agbẹnusọ Shehu Sani

Image copyright Sani
Àkọlé àwòrán Idi ti EFCC ṣe mu Sheu Sani S'ahamọ

Àjọ tó n gbógun ti lílu owó ìlú ni pònpó (EFCC) ti fi ọwọ́ òfin mu sẹnatọ to n soju ẹkun aarin gbùngbùn Kaduna tẹ́lẹ̀ri Sehu Sani.

Wọn ni ẹsun fún ilọnilọ́wọ́ gbà àti lílo orukọ èèkan ilú lu jìbìtì ni àwọn muu fun.

Ìròyìn sọ pé àjọ náà mú Sani ni ọjọ iṣẹ́gun nílùú Abuja pé ò n lò orúkọ adelé ajọ EFCC ọgbẹ́ni Ibrahim Magu láti gba owó tabua lọ́wa àwọn aará ìlú.

Lára rẹ̀ ni bi Sani ṣe gba ẹgbẹ̀run lọ́nà ogún dọla lọ́wọ́ oníṣòwò ọkọ kan, Alhaji Sani Dauda to jẹ oludári ASD Motors to si ti fun ni ẹgbẹ̀run mẹ́wàá dọ́la ko to lọ fi ẹjọ sun àjọ EFCC.

Ẹnikan fidi rẹ̀ múlẹ pẹ: "ASD motors, iyẹn Alhaji Sani Dauda, fẹ́jọ sùn pé Sani gba ẹgbẹ̀run mẹ́wàá dọla lọ́wọ oun nítori pé ó sọ pé òun jẹ ọ̀rẹ́ tímọtímọ pẹ̀lú adele alaga àjọ EFCC."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAkure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Wọ́n mú u sùgbọ́n wọ́n gba oniduro rẹ̀ lẹ́yìn ti wọ́n ri ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá dọla gbà pada, wọ́n ni ko maa yọju si akata wọn loorekoore sùgbọ́n kaka bẹẹ ko jẹ́ ki ẹnikẹni ri òun."

Ati pe wọn ni Sani n fọ́wọ́ sọyà pe ọ̀rẹ tímọtímọ ni òun pẹ̀lú Ibrahim Magu, òun si le ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bọ lọ́wọ́ gbogbo ìwádìí àti ijiya ti wọ́n le sálabapade lọ́dọ̀ àjọ EFCC".

Iroyin ni Dauda fi ọ̀rọ̀ naa to EFCC leti pé ẹgbẹ̀run lọ́na ogun dọla ni Sani bèèrè fún láti fi sọwọ si Magu ki ọ̀rọ̀ náà ba le di igbàgbé

Sùgbọ́n oluranlọ́wọ́ pàtàkì si Sani, Ahmed Suleiman bu ẹnu àtẹ lu mimu ti wọ́n mu ọmọ ilé ìgbìmọ aṣofin tẹ́lẹ́ rí naa pe wọn ko tii wadii ootọ bi o ti yẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2020: Oloye Awurela Ifaleke ti wúré ọdún ìgbéga fún kóówá

Suleiman ni sẹnatọ náà kan lọ lati lọ ba ASD kẹdun lori wàhálà ti o ni pẹ̀lú àjọ EFCC, lẹ́yìn náà ni ASD ri ọkọ píjo rẹ̀ to sì gbàá nimọràn pé ko paarọ rẹ̀ si èyi to tún gbayi jù bẹ́ẹ lọ.

O ni eyi ni Sani fesi si pe oun ko ni owo fun eyi lọ́wọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

ASD lo mú àbá wá wi pé Sẹnatọ le maa san owo náà díẹ̀diẹ̀ ti sẹnatọ naa si gba bẹ́ẹ̀, nígbà ti o délé o lọ fun ASD ni ẹgbẹ̀run méjìlá dọla ti ASD si fun un ni edà iwe fun owo to san.

Agbẹnusọ sẹnatọ náà ni alágàbangebe ni ASD àti pé o ti gba ki wọ́n lo òun fún oṣèlú, sùgbọ́n ni bayii tọ́rọ̀ ti di ti ọlọpàá ilé ẹjọ ni yóò yanju gbogbo rẹ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'