Prince Harry and Meghan: Ọbabinrin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ọmọọba Harry yóò sèpàdé ní Ọjọ́ Ajé

Ìdile Ọba Ilẹ Gẹẹsi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìpàdé náà kò sẹ̀yìn bí Ọmọbakùnrin Harry àti ìyàwó rẹ̀, Meghan Markle se ní àwọn fẹ́ fi ipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òkan gbòógì nínú ìdílé ọba.

Ọbabinrin Ilẹ Gẹẹsi ti ke pe awọn ọmọoba fun ipade ni Ọjọ Aje lati jọ fọrọ-jomitoro ọrọ papọ lojukoju.

Ọrọ naa yoo da lori Ọmọbakunrin Harry ati iyawọ rẹ, Meghan Markle ati bi wọn yoo ṣe ma a lo ipo wọn gẹgẹ Duke ati Duchess agbegbe Sussex.

Ile Ọbabinrin Elizabeth to wa ni Norfolk ni ipade naa yoo ti waye, eleyii ti wọn pe ni ipade 'Sandringham summit'.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọbabinrin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ọmọọba Harry yóò sèpàdé ní Ọjọ́ Ajé

Iroyin lati Ile Ọba sọ wi pe Ọmọbakunrin Harry, Duke ti Cambridge ati Ọmọba ilu Wales ni yoo wa ni ibi ipade naa, nigba ti Meghan yoo darapọ mọ ipade naa lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ.

Laipẹ yii ni Ọmọbakunrin Harry ati iyawọ rẹ, Meghan Markle sọ wi pe awọn fẹ yẹba diẹ gẹgẹ bi ọkan gboogi ni idile ọba Ilẹ Gẹẹsi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'

Ọmọọba Harry ko si ninu ẹni to le e jẹ ọba Ilẹ Gẹẹsi

Ọmọbakunrin William to jẹ ẹgbọn Harry ni o ti fihan gbangba gbe aarin wọn ko gun, lẹyin to sọ wi pe, ọpọ igba ni oun ti ṣe egbelẹyin fun aburo oun, amọ oun ko ṣe mọ, nitori ọrọ awọn ti n tako ara wọn.

Ireti ni pe ipade naa yoo fi lgbesẹ to kan lede pẹlu igbeṣẹ awọn mejeeji.

Ipade naa yoo tun wa ọna abayọ si ibasepo ati ifọwọsowọpọ ti yoo wa laarin Ọbabinrin Elizabeth ati Ọmọbakunrin Harry ati iyawo rẹ.

Iroyin fikun pe o ṣeeṣe ki idiwo ati idena o wa ninu ipade naa, ti yoo jẹ ọna lati wa ọna abayọ si ọrọ naa.

Bakan naa ni wọn yoo ma a gbe yẹwọ bi awọn mejeeji yoo ṣe ma agbe ile okeere, lai lo owo ori awọn eniyan Ilẹ Gẹẹsi basubasu.

Ti a ko ba gbagbẹ, Ọmọbakunrin Harry ati iyawo rẹ Meghan Markle ni awọn fẹ fi ọwọ ara awọn ṣiṣẹ, ti awọn yoo si ma a tọju ara wọn nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo fọ́ lójú ṣùgbọ́n mo mọ gbogbo irinṣẹ́ tí mo fi ń ṣe mọkalíìkì'