Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Mo fẹran Iyán ati ọbẹ ẹfọ riro pupọ- Bakare Mubarak

Arinrinoge to ga julọ nilẹ Adulawọ, Mubarak Bakare ba BBC lalejo nibi to ti sọ bi oun ṣe bẹrẹ irin ajo rẹ lẹnu iṣẹ arinrinoge.

O sọrọ nipa awọn ipenija iṣẹ rẹ ati pataki gbigba kadara lori bi Olorun ṣe dani.

Bakare tun gba ijọba Naijiria ni imọran lati tubọ mojuto irinajo afẹ ni Naijiria bii ti awọn orilẹ-ede ilẹ okeere

Mubaraq mẹnuba awọn ami ẹyẹ to ti gba ati awọn iṣẹ to ti ṣe to lami laaka

Bakan naa lo gba awọn ọdọ ni imọran lati gbajumọ iṣẹ ọwọ wọn nitori pe atẹlẹwọ ẹni, ni kii tan ẹnii jẹ.

Production:Yemisi Oyedepo àti Joshua Akinyemi