Operation Amotekun: Àwọn ajínigbé ṣá mi láàkéé nínú igbó, ìdásílẹ̀ Amotekun dára

Olu Falae Image copyright Other

Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AD tẹlẹ ri, Oloye Olu Falae naa ti da si ọrọ ẹṣọ ilẹ Yoruba, ''Amọtẹkun tawọn gomina apa iwọ oorun Naijiria ṣẹṣẹ ṣe ifilọlẹ rẹ.

Oloye Falae ni bo yo amọtẹkun ba ofin tabi ko ba ofin mu, awọn agbẹjọro nikan lo le sọ.

Ṣugbọn Oloye Falae ni anfaani to pọ wa ninu ifilọlẹ ẹṣọ eleto aabo Amọtẹkun nitori eto aabo to mẹhẹ kaakiri orilẹede Naijiria.

Falae fikun ọrọ rẹ pe laye ọjọ-un, ilu kọọkan lo ni ọlọpaa tirẹ, o ni ofin wa fun igbayegbadun awọn ilu ni kii ṣe pe awọn araalu lo wa fun ofin.

Oloye Falae ni lẹyin iriri oun lọwọ awọn ajinigbe ninu igbo fun ọjọ mẹrin nibi ti wọn ti ṣa oun laakẹ, o ni o ṣe pataki lati wa nnkan ṣe si ọrọ eto aabo to mẹhẹ.

O ni ẹgbẹẹgbẹrun un eeyan lawọn ajinigbe ti ṣe leṣe nitori ọrọ eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.

Akeredolu, Oyetola, àtàwọn míì sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí ìjọba àpapọ ní Amotekun kò bá òfin mu

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti fesi si ọrọ agbẹjọro ijọba apapọ, Abubakar Malami.

O fèsì si ọrọ ti Malami sọ pe idasilẹ ikọ Amọtẹkun ko ba ofin Naijiria mu.

O ni bo tilẹ jẹ pe Malami lẹtọ lati gba ijọba apapọ lamọran nipa ọrọ ofin, o han kedere pe inu ofiisi rẹ kọ ni wọn ti n ṣe ofin Naijiria.

Image copyright "others
Àkọlé àwòrán Akeredolu fún Malami lésì lẹ́yìn tó ní ìdásílẹ̀ Amotekun kò bá òfin mu

Akeredolu wa sọ pe awọn gomina ilẹ Yoruba yoo ṣe ipade laipẹ, ti wọn yoo si gbe igbesẹ to tọ lori ọrọ ti Malami sọ, pe ikọ Amotekun ko ba ofin ilẹ Naijiria mu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Bakan naa, gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola sọ pe ipinnu lati da ikọ Amotekun silẹ jẹ ajọsọ laarin awọn gomina mẹfa to wa ni ilẹ Yoruba.

Nitori naa, igbesẹ yowu ti wọn maa gbe yoo jẹ eyi ti gbogbo wọn jọ fimọ ṣọkan nipa rẹ.

O ni ko si ipinlẹ kankan nilẹ Yoruba ti yoo da gbe igbesẹ kankan lori ọrọ ijọba apapọ ọhun.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yoruba lẹ́tọ̀ọ́ láti dá ikọ̀ Amotekun sílẹ̀ - Itse Sagay

Àkọlé àwòrán Ọrọ Amọtẹkun ti di ija gbogbo eeyan to fe eto aabo to peye

Ẹgbẹ Agbẹkọya ti sọrọ lori awuyewuye ti Agbẹjọro agba fun ijọba apapọ sọ pe Amọtẹkun ko ba ilana ofin Naijiria mu.

Agbẹkọya ilẹ Oodua ti ni ko si ọrọ nibẹ rara nitori ko si ijọba to le sọ pe ki onikaluku ma pese abbo fawọn eniyan rẹ bi o ṣe yẹ.

Oloye Kamorudeen Okikola to jẹ aarẹ Agbekọya ni ki Malami ko ila kuro lẹkọ nitori pe ẹkọ ko kọ ila rara.

Kini Afẹnifẹre n sọ lori Amọtẹkun?

Afẹnifẹre to jẹ ẹgbẹ ohùn iran Yoruba ti fi sita pe ki ẹni ti Amọtẹkun ko ba tẹ lọrun gba ile ẹjọ lọ.

Afẹnifẹre ni ko si ninu ofin Naijiria pe ki gomina kọkọ lọ maa gba aṣẹ lọwọ agbẹjọro agba fun Naijiria ko too pese eto aabo to peye fun awọn eniyan rẹ.

Ọgbẹni Yinka Odumakin to jẹ alukoro agba ẹgbẹ naa ni ohun ti ijọba ko fi fopin si Myetti Allah ati awọn darandaran to n gbe ibọn kiri naa lo difa pe wọn ko le fopin si ikọ Amotekun.

Wọn tun beere lọwọ Malami pe agbara wo ni ọọfiisi rẹ ni lati mọ ọna eto aabo to yẹ fun iran Yoruba lasiko yii?

Kini ero awọn olori ẹkun Guusu àti Aarin Gbungbun Naijiria?

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ agba yii fi sita ti awọn wọnyii fọwọ si ni wọn ti ni ko tọna lati dẹkun ọna eto aabo iran kan tabi omiran.

Yinka Odumakin (fun guusu iwọ oorun Naijiria); Ogagun CRU Iherike (fun Guusu Ila oorun Naijiria); Senetọ Bassey Henshaw (fun Guusu-Guusu) àti Omowe Isuwa Dogo (fun Aarin Gbungbun) lo fọwọ sii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLebanon: Iṣẹ́ tí kòsí ní Naijiria, la ṣe lọ ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ ní Lebanon

Wọn ni ọrọ Abubakar Malami yii kudiẹ kaato nitori pe o dabi i ti ẹni to fẹ ṣe aṣilo ipo tabi ọọfiisi rẹ ni.

Wọn ni igbesẹ to yẹ ki Malami gbe ni pe ko fi iṣọkan han laarin awọn eniyan Naijiria ni lai dẹyẹ si iran kankan

Image copyright @ekitistategov
Àkọlé àwòrán Ọjọ kẹsan an Oṣu Kinni ọdun yii ni awọn gomina ipinlẹ mẹfa lati ilẹ Yoruba ṣe ifilọlẹ ikọ Amọtẹkun nilu Ibadan

Ọ̀rọ̀ rírùn ni ìjọba àpapọ̀ ń sọ lórí ìdásílẹ̀ ikọ̀ Amotekun - Itse Sagay

Àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ti ń fi èròńgbà wọn léde lẹ́yìn tí agbẹjọ́rò Abubakar Malami sọ pé ikọ̀ Amọtẹkun kò bá òfin mu.

Alaga igbimọ ijọba apappọ lori igbogun ti iwa ibajẹ, Ọjọgbọn Itse Sagay ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu agbẹjọro ijọba apapọ, Abubakar Malami, lẹyin to sọ pe ikọ Amọtẹkun ko ba ofin mu.

O ni ki awọn gomina ipinlẹ Yoruba ma ka ọrọ ti adajọ agba naa sọ nipa ifilọlẹ ikọ Amotekun si.

Sagay sọ pe awọn gomina ọhun ko nilo lati kọkọ gba aṣẹ lọwọ Malami ki wọn to wa ọna ati daabo bo agbegbe wọn.

Ṣaaju ni ẹgbẹ to n risi idagbasoke ilẹ Yoruba, Yoruba Council of Elders ti bu ẹnu ẹtẹ lu ohun ti agbejọro ijọba naa sọ lori idasilẹ ikọ Amọtẹkun to wa fun eto aabo ilẹ Yoruba.

Image copyright facebook/Amotekun
Àkọlé àwòrán Ọjọ kẹsan an Oṣu Kinni ọdun yii ni awọn gomina ipinlẹ mẹfa lati ilẹ Yoruba ṣe ifilọlẹ ikọ Amọtẹkun nilu Ibadan

Akọwe ẹgbẹ YCE, Dokita Kunle Olajide ni ọrọ ti agbẹjọro agba fun ijọba apapọ sọ lori ikọ naa ko daa to.

O sọ pe ofin orilẹ-ede Naijiria faaye gba ipinlẹ kọọkan pẹlu aṣẹ lati da aabo bo awọn ara agbegbe rẹ labẹ iṣejọba alagbada.

Ọjọ kẹsan an, Oṣu Kinni ọdun yii ni awọn gomina ipinlẹ mẹfa lati ilẹ Yoruba ṣe ifilọlẹ ikọ Amọtẹkun nilu Ibadan.

Ọpọ awọn eeyan jankan nilẹ Yoruba lo si peju sibi ifilọlẹ ọhun.

Awọn ọmọ Yoruba n pariwo pe eto aabo ilẹ Oodua n fẹ amojuto

Àkọlé àwòrán Awa ko ni gba ọrọ MAlami lori Amọtẹkun