Lassa Fever: Wo iye ibùdó ìtójú ibà Lassa tó wà ní Nàìjíríà

Aworan ikilọ Lassa Fever Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Arábìnrín kan kú látàrí àìsan Lassa ní ìpínlẹ̀ Enugu lẹ́yìn tí wọn kò tètè rí ilé ìwòsàn láti ṣe àyẹ̀wò

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ti sọ wi pe ile iwosan mẹtadinlogun lo wa fun itọju aisan naa.

Ajọ NCDC sọ eyi latari bi iye awọn eniyan to ti ku nipa aisan iba orẹrẹ Lassa Fever ṣe n pọ si i kaakiri awọn ipinlẹ ni Naijiria.

NCDC lasiko ti wọn n ṣe ipade pẹlu awọn onimọ nipa aisan Lassa n woye boya ki wọn kede eto pajawiri nitori aisan Lassa naa.

Lọwọlọwọ ile iwosan mọkanlelogun lo wa kaakiri ipinlẹ mẹtadinlogun lorilẹede Naijiria lo ni awọn iwosan ti wọn nilo lati ṣe itọju ati ayẹwo fun ẹni ti o ba ni aisan naa.

Yatọ si awọn ile iṣẹ iwosan yii, awọn ibudo ti wọn ti n ṣe ayẹwo ẹjẹ lati mọ boya eniyan ni aisan naa wa ni ipinlẹ marunlorilẹede Naijiria, awọn si ni:

  • National Reference Laboratory, Gaduwa, FCT.
  • Irrua Specialist Teaching Hospital, Edo State.
  • Lagos University Teaching Hospital (LUTH).
  • Federal Teaching Hospital, Abakaliki, Ebonyi state.
  • Federal Medical Centre Owo, Ondo state.

Ajọ eleto ilera NCDC sọ wi pe awọn gbọngan ayẹwo naa ṣe pataki lati le tete mọ boya eniyan ni aisan iba Lassa.

Wọn ni ireti pe eto ilera yoo le tete wa fun awọn ti wọn ba ni aisan naa ki o ma baa jọ si iku ọpọlọpọ eniyan.

Ile iṣẹ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni awọn n ṣe igbelẹyin fun awọn ipinlẹ to ni ile iwosan ati awọn ile iwe giga ti wọn ti n kọṣẹ imọ eto iwosan ni orilẹede Naijiria lọna ati pese iwosan to peye lati koju aisan iba Lassa naa.

Image copyright Getty Images

Bakan naa ni wọn fikun un pe awọn n ṣe eto idamọran fun awọn eniyan ati eto pajawiri lati le koju ajakalẹ arun naa.

Aisan Lassa n damu ọpọlọpọ orilẹede ni iha iwọ oorun Afrika, ti o si n peleke sii ni Osu Kọkanla si Osu Karun un to jẹ igba ẹrun ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKí lo tíì rí nípa Amotekun? Ẹ sùnmọ́bí, ẹ wo gbankọgbì!