Visa Policy: Wo àwọn nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa gbígba físà Nàíjíríà

Awọn eeyan to n wọle si papakọ ofurufu

Oríṣun àwòrán, @VisasAndTravels

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti gbe ilana tuntun fun iwe asẹ iwọlu si orilẹede Naijiria f'ọdun 2020 jade f'aye ri l'ọjọ Iṣẹgun.

Aarẹ Buhari sọ pe, Ilana fifunni ni iwe asẹ iwọlu fisa NVP 2020 naa yoo pese awọn ọna lati so ilẹ Africa pọ; idasilẹ eto fifun awọn to ba ni iwe irinna idanimọ orilẹ-ede Africa, to si wa fun abẹwo ọlọjọ diẹ ni Naijiria ni fisa ti wọn ba gunlẹ si Naijiria.

Gẹgẹ bi aarẹ ṣe sọ, ilana gbigba Fisa tuntun yii yoo ran eto okoowo lọwọ ni Naijiria; ti yoo si tun mu ki irinajo igbafẹ o pọ si.

Bakan naa lo ni yoo fa oju awọn oludokowo lati ilẹ okeere mọra; ti yoo si tun mu ki irẹpọ o wa nilẹ Africa lai ba eto aabo Naijiria jẹ.

Oríṣun àwòrán, twitter/Presidency

O fi kun un pe ilana tuntun naa, NVP 2020 yoo tun wulo lati fa oju awọn ọlọpọlọ pipe ati akọṣẹmọṣẹ ti yoo ran awọn to wa ni Naijiria lọwọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni ajọ to n ri si iwọle-wọde ni Naijiria ti sun ipele fisa to wa nilẹ tẹlẹ lati mẹfaa si mọkandinlọgọrin.

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@BASHIRAHMAAD

Wọn ni awọn se bẹẹ lọna ati ri i daju pe fisa ti wọn ba fun eeyan wa ni ibamu pẹlu idi to fi rinrinajo wa si Naijiria.

Awọn nkan to yẹ ko o mọ nipa iwe asẹ iwọlu tuntun ni Naijiria:

  • Ọdun 1958 ni Ilana fifun ni ni Fisa bẹrẹ labẹ ofin irinna oyinbo amunilẹru.
  • Ilana tuntun yi, NPV 2020 jẹ ọkan lara eto atunṣe si iwọle-wọde lẹnu ibode Naijiria fun ọdun 2019 si 2023.
  • Orilẹ-ede Naijiria ti ni eto igbalode fun gbigba Fisa; Eto yii yoo so akọsilẹ eniyan to ba gba fisa mọ gbogbo fisa ti wọn ti fi sita.
  • Bakan naa ni yoo tun mu ki o ṣeeṣe lati ri iye igba ti ẹni naa ti kọwe beere fun fisa.
  • Akọsilẹ igbalode yii tun le ṣe ayẹwo abẹnu lori ẹnikẹni ti awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ abẹle tabi ilẹ okeere ba n wa.
  • Labẹ eto NPV 2020 yii, Ileeṣẹ to n risi iwọle-wọde ni Naijiria ti sun ipele fisa mẹfa to wa tẹlẹ si mọkandinlọgọrin.
  • Eyi yoo ri i daju pe fisa ti wọn ba fun eeyan wa ni ibamu pẹlu idi fun irinajo.
  • Ilana Fisa NVP 2020 yii yoo ri daju pe eto aabo dara si, ti yoo si tun mu ki akoyawọ o wa, ati igbogun ti iwa ibajẹ to maa n waye lasiko ti awọn arinrinajo ba fẹ ẹ gba fisa nitori pe adinku yoo ba fifoju rira ẹni laarin awọn ti ọrọ kan.