Otedola Bridge: Àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ti gbé Ọkọ̀ agbépo tó dànù kúrò lọ̀ná

Otedola

Ajọ to n risi irinna ọkọ oju popo ti ni awọn ti gbe ọkọ agbepo to ja naa kuro ni oju popo.

Eyi ko sẹyin bi ọkọ agbepo to ja lati ara ọkọ ti naa ṣe da sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ ni afara ọtẹdọla ni ipinlẹ Eko.

Ọpọlọpọ ọkọ to n jade kuro ni ilu Eko ni sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ti fa wahala fun.

Awọn oṣiṣẹ pajawiri ati ajọ awọn òṣìṣẹ́ àjọ ojú pópó fi lede wi pe ohun gbogbo ti pada si ipo lẹyin ti wọn gbe ọkọ naa kuro loju popo, ti awọn ọkọ si ti bẹrẹ si ni rin loju ọna naa pada.

Awọn ajọ naa wá níbẹ̀ láti bójútó súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ náà, ati lati ri daju pe epo bẹntiroolu to wa ninu ọkọ naa ko da ijamba ina silẹ.

Bakan naa ni wọn ti rọ awọn arinrinajo lati ṣe pẹlẹpẹlẹ ni agbeegbe naa, ki ohun gbogbo le lọ leto leto.

Ọpọlọpọ igba ni awọn ọkọ nla ma n da sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ ni agbeegbe afara Otedola naa, ti ijamba ina si ti ṣẹlẹ nibẹ lọpọ igba.