Lagos -Ibadan Express: Súnkẹ́rẹ fakẹrẹ ọkọ òpópónà marosẹ̀ tòní tún kọ sísọ

Lagos -Ibadan

Oríṣun àwòrán, Goldmyne

Àkọlé àwòrán,

Lagos -Ibadan Express: Súnkẹ́rẹ fakẹrẹ ọkọ òpópónà marosẹ̀ tòní tún kọ sísọ

Òpópónà Eko si Ibadan ni àwọ́n ènìyàn tún ji si pe o ti di pa ni òwúrọ̀ oni, ti ọ̀ps ko si ni ìrèti àsìkò ti wọ́n yóò de ẹnu iṣẹ́ wọ́n.

Ìròyìn sọ pe àwọn ọkọ to n bọ wá si ilú Eko lati ilú Ibadan ko le wọlẹ pàápàá jùlọ lati ori afára Kara, bákan náà ni àwọn to n lọ si ìlú Ibadan náà ko ni ànfani láti tẹ̀síwájú.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ to yẹ ki o mú ọ̀rọ̀ náà lójúùtú lo ti wà ni ẹnu iṣẹ́.

Àkọlé fídíò,

Mi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babalawo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré - Fadeyi Oloro

Oríṣun àwòrán, Goldmyne

Àkọlé àwòrán,

Lagos -Ibadan Express: Súnkẹ́rẹ fakẹrẹ ọkọ òpópónà marosẹ̀ tòní tún kọ sísọ

Ìròyìn to tẹ BBC lọ́wọ́ ni pe, mọto to gbé ẹpo kan ló gbaná ni dédé ààgo méje alẹ ana ọjọ Isẹgun lópòpóna Lagos-Ibadan Express, èyí sì ló ṣe okùnfà súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀.

Iwáju ilé gagara ti wọ́n n pè ni Opic lágbàgè Iṣẹri ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáye,ọ̀ps àwọ̀n ènìyàn lo n fi ẹsẹ̀ rin nláàrin igboro nítori ko si bí wan yóò ṣe ri mọ́tò.

Oríṣun àwòrán, Goldmyne

Àkọlé àwòrán,

Lagos -Ibadan Express: Súnkẹ́rẹ fakẹrẹ ọkọ òpópónà marosẹ̀ tòní tún kọ sísọ

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn lọ́ri àtẹjuiiṣẹ́ twitter lo ti n sọ bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe n lọ lọ́wọ́lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Goldmyne

Àkọlé àwòrán,

Lagos -Ibadan Express: Súnkẹ́rẹ fakẹrẹ ọkọ òpópónà marosẹ̀ tòní tún kọ sísọ

Kíní àwọn ènìyàn ń sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Ọ̀pọ̀ lo n da èbi ìṣẹ̀lẹ̀ yiì ru ìjọba ààrẹ aná Olusegun Obasabjo, Yara'Adua àti Jonathan.