Fadeyi Oloro Yoruba Films: Mi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babaláwo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré

Fadeyi Oloro Yoruba Films: Mi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babaláwo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré

"Emi Fadeyi Oloro, emi arisa ina ako tagiri ede werepe ti o nibi aa gbamu gbogbo ara ló fi ń jó 'ni. Ẹní mọ̀ mí ò kò mi, ẹni kò mí ò mọ̀ mí, èmi ati kékeré m'ojú ewé, sanpọna ò gbóògùn".

Baba Fadeyi Oloro gba alejo BBC Yoruba nile rẹ. O bu ẹnu atẹ lu nkan ti ọpọ eniyan n ro ti wọn si n sọ nipa rẹ.

"Àwọn ọ̀tá fẹ́ kí n kú ni ṣùgbọ́n Ọ̀lọ́run mi ò jẹ́, ẹ ó bẹ̀ mi kúrò láyé ni". Fadeyi Oloro kẹnu bọ ọfọ tan ni pẹrẹwu gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe ninu ere lai fi ọkan pe meji rara.

Ọfọ ṣi ki si baba lẹnu, o sọ ọ tan lo ni ohun ti di Pasitọ bayii ki a sọ nkan mii.