Ash Wednesday: Àyájọ́ ọjọ́ eérú t'ọdún yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀

Ọjọ eeru

Ọjọ mimọ ni ayajọ ọjọ eeru jẹ lagbaye fun awọn Kristẹni gẹgẹ bi ọjọ ti wọn n pe ni akoko Lẹnti eyi tii ṣe akoko awẹ ati adura.

O jẹ akoko ironupiwada fun ọsẹ mẹfa ṣaaju ọdun ajinde. Aawẹ yii maa n waye fun ogoji ọjọ gẹgẹ bi Jesu Kristi ti gba a ninu bibeli.

Lasiko yii lọdun ti a wa yii, awọn ọmọ ijọ Katoliki ni Naijiria n lo ọjọ eeru lati fi ṣ'ọfọ awọn to fara gba ninu gbogbo iwa ipa to damu orilẹede yii.

Biṣọọbu agba patapata ti ijọ Katoliki ni ipinlẹ Eko, Arch bishop Adewale Martins sọ fun BBC pe ipade awọn Biṣọọbu ti wọn ṣe kọminu gidi gan lori iṣoro aabo lorilẹede Naijiria.

"O ba ni ninu jẹ gan pe ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo n la ọpọlọpọ iwa ipa kọja latọdọ awọn ẹgbẹ bii Boko Haram, ISWAP, awọn Fulani darandaran ati awọn ẹgbẹ agbesunmọmi mii.

Biṣọọbu ni tori naa lawọn ṣe ni awọn yoo ṣe ọjọ eeru wọn lati gba adura fun awọn to fara gba ninu ikọlu ati adura fun ẹmi awọn to ti papoda.

"A ni ki awọ́n eeyan wọ aṣọ dudu, ẹgba ọwọ rọba dudu tabi ohunkohun lati fi han pe a n ṣe ọfọ". Biṣọọbu agba tun ni igbesẹ yii wa lati fun'pe si ijọba lori ọ̀rọ̀ yii.

"O tun jẹ ọna ti a fẹ gba lati ke si ijọba pe inu wa ko dun pe ijọba ko ṣe to lati da abo bo ẹmi ati dukia awọn araalu pẹlu gbogbo owo ti wọn ti rọ sinu ọrọ naa ati idaniloju ti wọn n fun wa nigbakugba ti ikọlu ba ṣẹlẹ si awọn eeyan wa.

Ju eyi lọ, a tun ro o wi pe o ṣe pataki fun awọn orilẹede agbaye lati ri i pe Naijiria n woye pe wọn ni imọlara oun ti a n la kọja ki wọn si da si ọrọ naa ki wọn ba wa yanju iṣoro yii tori o da bii wi pe iṣoro yii ti tayọ ijọba atawọn oṣiṣẹ alaabo orilẹede yii".

Biṣọọbu agba ni pẹlu inu mimọ ni ohun ti awọn n ṣe lati fa oju ijọba sinu iṣẹlẹ ọhun kii ṣe lati tako ijọba rara.