Kano: Òbinrin kan fẹ́ ọkọ meji, ọkọ ní ọdún méjì péré ni òun fi rìnrìn àjò

Igbeyawo Hausa Image copyright other
Àkọlé àwòrán Òbinrin kan fẹ́ ọkọ meji, ọkọ ni ọdun meji péré ni òun fi rin irin àjò

Àwọn ọlọpàá Hisbah ni ìpińlẹ̀ Kano ti n ṣe ìwádìí ìgbéyàwó àjòjì kan to wáye, níbi ti òbìnrin kan ti fẹ́ ọkọ meji lásìkò kan náà.

Àjọ náà ni àwọn gba ẹ̀sùn láti ọ̀dọ̀ ẹni ọdun mọ́kànlélógòjì kan to n jẹ Bello Ibrahim pé ìyàwó òun Hauwa Ali ti ó ti fẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún ni oun ba to ti fẹ́ ọkọ míràn lẹ́yin ti òun de lati ibí ti o lọ fún ọdún méji lati gba ìtọju, o si ni àwọn méjèèji jọ ń gbe nínú ilé oun.

Gẹ́gẹ́ bi akọròyìn BBC to jábọ̀ ṣe sọ, ní pé ìsẹ̀lẹ̀ náà jẹ ìyàlẹ́nu fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wi pe obinrin kan fẹ́ ọkọ meji, ati pe Musulumi ni àwọn mẹtẹẹta ti ọ̀rọ̀ náà kan àti pé ẹsìn musulumi ko fààyè gba ki obìnrin fẹ́ ọkọ méjì.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo fẹ́ ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo lóríi ikú àìmọ̀dí tí wọ́n fi pa ọmọ mi'

Bello ni òun ti fẹ́ Hauwa láti ọdún mọ́kandilogun sẹ́yìn, Ọlọrun si fi ọmọ mẹfa ta àwọn lọ́rẹ, sùgbọ́n lẹ́yìn ti òun pada dé láti irinajo níbí ti òun ti lọ gba ìwòsàn lẹ́yìn ọdun meji.

" Mí o kọwé fi ìyàwó mi sílẹ̀, o rẹ mi ni mó si lọ si abúle kan ní ilú òdì keji lati gba ìtọju. Láti ìgbà ti mo ti lọ ko wá láti bẹ̀ mi wò, à si ti fẹ́ra wa láti bi ọdún makàndinlogun sẹ́yìn, lóòtọ o wá si àbúle wa nibi ti mọ wà léèkan sùgbọ́n o sọ fún mi pe kìí ṣe èmi ni òun wá wa, sùgbọ́n ọmọ òun ọkùnrin. Jẹ́ kín n sọ fún ọ mi o kọ̀wé fi ìyàwó mi sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi ǹkan to n sọ kiri, sùgbọ́n to ba sọ bẹẹ, ẹ jẹ ki o lọ mu ẹlẹri tirẹ̀ wá, sùgbọ́n o dá mi lóju pe mi o sọ bẹẹ fún. eyí ni alaye Bello ọkọ àkọkọ.

Ní ti ọkùnrin keji, o ti fi ààke kọri pé oun gan ni ojúlówó ọkọ, ati pe òunm fẹ́ lẹ́yin ti ọkọ rẹ kọọ silẹ̀.

" Adamawa ni mo wà nígba ti Hauwa pe mi nípia ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó ati pe ki n fi owó orí òun ránsẹ́, èyi to jẹ́ ẹgbẹ̀run lọ́nà ogun Naira, èmi àti Hauwa ti wá láti ìgbà tó ti pẹ́. Alaye ti Bala Ibrahim to jẹ ọkọ keji ṣe ni èyí.

Nínú ọ̀rọ̀ ti Hauwa Ali " Nígbà ti mo sàlàye fún àwọn òbi mi pe mo fẹ fẹ́ ẹlomiràn, wọ́n kò bá mi jà si, súgbọ̀n wọ́n ni ki ni yoo ṣẹlẹ̀ ti Bello ba pada de ti o si sọ pe oun ko ks mi sílẹ̀. Ẹgbọ́n mi ọkùnrin nítirẹ ni òun ko fọ́wọ́ si àfi ti Bello ba de ti awọn si gbọ́ ọ̀rs tirẹ̀ nítorimpe ti o ba sọ pe òun ko kọ mi silẹ̀ ǹkọ, sùgbọ́n mo tẹ̀síwáju lati fẹ́ Bala a sì jọ ń gbe ilé Bello ti o jẹ́ ibi kan soso ti mo ni lati gbe, nítori mi o le fi àwọn ọmọ mi silẹ̀.

Adari àjọ Hisbah ni àwọn ọkùnrin mejeeji ni wọ́n ni àwọn jẹ́ ọkọ Hauwa nítori náà àwọn yóò gbe ẹjọ náà lọ si kóòtù ti ìwádìí ba ti parí.