Boko Haram: Serap kọ̀ jálẹ̀ lórí bí ìjọba ṣe fẹ̀ rán Boko Haram nílé èkọ́ l'òkun

Awọn ọmọ Nigeria n yayọ isẹgun nigbo Sambisa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọmọ ogun Naijiria ko sinmi lati fẹyin Boko Haram janlẹ.

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, Serap ti kọju agan si igbesẹ ijọba lati ṣe abadofin ti yoo fun awọn ikọ Boko Haram to ba ronupiwada ni anfaani lati lọ si oke okun lọ ka iwe.

Abadofin naa wa ni ile igbimọ asofin agba lorilẹede Naijiria.

Ninu lẹta ti igbakeji adari ajọ Serap, Kolawole Oludare kọ lo ti kesi aarẹ ile asofin agba, Ahmed Lawan, ki o ma ṣe jẹ ki abadofin naa kẹsẹ jari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Serap ni ki ile igbimọ aṣofin maṣe gba abadofin naa, to n pe fun ipese imọ ẹkọ loke okun fun awọn ikọ Boko Haram to ba rọnupiwada laaye, amọ ki wọn fi aye silẹ fun eto ti yoo kọ wọn ni ọna lati gbe igbe aye to dara, lọna to ba ofin mu.

Wọn ni abadofin naa tẹ oju ofin mọlẹ, bẹẹ lo si bu ẹnu atẹ lu iṣoro ti ikọ Boko Haram ti da silẹ fun awọn ẹbi ati ara awọn ti ikọ agbesunmọmi naa ti pa.

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán,

Awọn ologun Naijiria ko sinmi lati fẹyin Boko Haram janlẹ.

‘Pipe awọn ikọ Boko Haram ni awọn ajijagbara tẹlẹri bu ẹnu atẹ lu gbogbo iwa apaniyan ati iwa ọdaran, to fi mọ ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan ti wọn ti sọ di alainile mọ nitori iṣe wọn ni ẹkun ariwa orilẹede Naijiria.’

Serap ni ohun ti ko boju mu ni ki ijọba Naijiria gbe eto ẹkọ to yẹ fun awọn ọmọ Naijiria, ti wọn ko fun wọn lati gbe fun awọn agbesunmọmi to ronupiwada.

Ajọ naa fikun wi pe, ti ijọba Niajiria ba tẹsiwaju lati sọ abadofin naa di ofin, yoo tẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ, bẹẹ ni yoo si da yanpon-yanrin silẹ fun awọn ara ilu, eleyii to le mu ifasẹyin ba idagbasoke orilẹede Naijiria.