Coronavirus: Ẹ wo ohun tí ààrẹ Buhari sọ lórí aáyan ìjọba láti dènà Coronavirus

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuahri

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kilọ fun awọn Niajiria lati maṣe paya lori aarun Coronavirus to n ja rain nilẹ.

Buhari sọ eyi lasiko to fi atẹjade lede lati ẹnu oluranlọwọ pataki rẹ, Malam Garba Shehu ni lọjọ Aiku.

O ni ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun nipa iroyin pe, Coronavirus ti wọ ipinlẹ Eko lati ọdọ ọmọ ilẹ Italy to wa ṣiṣẹ ni ileeṣẹ Lafarge Cement ni ipinlẹ Ogun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, aarẹ Buhari gboriyin fun ileeṣẹ eto ilera ti ijọba apapọ ati awọn ajọ miran, fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati tete gbogun ti itankalẹ arun naa ni ipinlẹ Eko ati Ogun.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Aarẹ Buhari wa kesi awọn ọmọ Naijiria ati ẹka ijọba to n risi arun coronavirus naa, lati ri wi pe awọn naa sa ipa wọn lati ma a ṣe akiyesi ayika wọn.

Bakan naa lo kesi wọn lati ri daju wi pe gbogbo aṣẹ ti ajọ to n risi eto ilera lagbaye, WHO pa fun wọn, nipa imọ toto ati fifọ ọwọ nigbakugba ni wọn tẹle.

Saaju ni ẹgbẹ oṣelu alatako lorileede Naijiria, Peoples Democratic Party, ti bẹnu atẹ lu aarẹ Muhamadu Buhari lori bi ko se sọrọ nipa aisan Corona Virus to wọ Naijiria.

Akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Kola Olongbondiyan ni aifini peni, aifeeyan peeyan ni iwa yii jẹ, bi aarẹ ko ti ṣe ti ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ.