Foluke Daramola Salako sọ̀rọ̀ nipa iku Pa Kasumu

Àkọlé fídíò,

Pa Kasumu tó ni ohùn ló lọ.Ohùn tó fi sílẹ̀ kò ní parẹ́.

Ẹ gbọ́ ǹkan ti àwọn òṣèré tíátà sọ nípa Pa Kasumu

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Ẹ gbọ́ ǹkan ti àwọn òṣèré tíátà sọ nípa Pa Kasumu

Gbájú gbaja eléré tíátà Adebayo Salami ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí ọ̀gá Bello lóti fi ìkíní ránṣẹ́ lori ikú ọ̀kan lára wọ́n to di olóògbé, Kayode Odumosu ti gbogbo ènìyàn mọ si Pa Kasumu.

Pa Kasumu to di olóògbé ni ọjọ́ kini oṣù kẹta lẹ́yìn àìsàn fún ìgbà díẹ̀ pe ọdún mẹ́rìndínláàdọrin ko to da gbere faye.

Nígbà ti Salami ń sọ̀rọ, ó sàlàyé pé ènìyàn to ṣee mú yangan ni Pa Kasumu nígbà ayé rẹ̀, o si tún jẹ́ ẹni ti o máa ń tèlé òfin àti ìlànà iṣẹ́ rẹ.

O ni agbà òṣèré yóò ṣe àfẹri Kayode Odumosu gidigidi bákan náà naa si ni àwọn alábaṣiṣẹ́pọ̀ rẹ.

Ọga Bello tẹsiwaju pe "O bani níńú jẹ́ sùgbọ́n ko sí ǹkan ti a le ṣe si àṣẹ ọlọrun, sáàjú àsìkò yìí ni a ti ń sáfẹri Pa Kasumu nítori o ti tó ọdun díẹ̀ sẹ́yìn ti ko ti le darapọ̀ mọ wa mọ láti ìgbà ti o ti ṣe aisan"

"Àdúrà mi ni pé ki ọlọrun tẹ si afẹ́fẹ́ rere ki o si tu àwọn ẹbi olóògbé nínú"

Àkọlé fídíò,

Pa Kasumu: Lere Paimo ní àìrìríjẹ́, àìrímú tàbí ìrònú má a ń jẹ́ kí ọjọ́ ogbó dagun

Toyin Adewale, Jaiye Kuti, Toyin Adegbola àti Yomi Fabiyi naa wà lára àwọn òṣère tí o ti ń ṣe elédè lẹ́yìn rẹ

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Fabiyi ni "Ẹni iyi àti ẹyẹ ni Pa Kasumu ti mo si ni ìfẹ́ rẹ̀ gídí, mo ń ṣelède lẹ́yìn rẹ̀ fún iṣẹ́ ribiribi to ṣe nínu iṣẹ́ tíatita."

Jaye Kuti náà ń daro

Toyin Adewale, ń ṣelede lẹ́yìn Pa Kasumu

Ní ti Toyin Adegbola, O ní "O dárọ Kayode Odumosu, kí Ọlọrun dẹlẹ fún kí o sì tẹ si afẹ́fẹ́ rere.

Foluke Daramola- Salako lo kéde ikú Pa Kasumu lori àtẹjiṣẹ́ instagram rẹ, gẹ́gẹ́ bo ṣe sọ, Kayode Odumosu ku ni ilé iwosan kan ni Abeokuta lásìkò àisan ranpẹ