Lagos: Àwọn olùgbé Kosofẹ́ figbe ta pé iná, bátírì, dígí, àti ẹ́ńjínì ọkọ̀ láwọn olè ń jí gbé lóru

Eko

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn olugbe agbeegbe Kosofe ni ijọba ibile Agboyi-Ketu ti ke sijọba ipinlẹ Eko lori iṣekupani to n waye ni gbogbo igba ni agbeegbe naa.

Awọn olugbe naa ni awọn ole ma n ba mọto awọn jẹ, ti wọn a si tu ẹya ara rẹ lọ.

Lara awọn to faragba ninu iṣẹlẹ naa sọ fun awọn oniroyin pe, awọn adigunjale naa ma n wọ asọ bi awọn ẹsọ alaabo to n kaakiri ni agbeegbe naa, ti wọn yoo fi raye wọle si agbeegbe yii lati ṣọṣẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn agbeegbe ti ọrọ naa kan ni Agbeegbe Iyanse, Onagoruwa, Kosofe ati Iyana School bus stop, tawọ̀n eeyan agbegbe naa si ni wọn maa n gba ohun ini awọn.

Wọn tiẹ fikun wi pe, awọn aidgunjale yii ti ji ẹya ara ọkọ to le ni mẹtala ni agbeegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Àwọn olúgbẹ́ agbégbé Kosofe ní ìjọba ìbílẹ̀ Agboyi-Ketu ti ké gbàjarè síta lórí àwọ̀n adigunjálè tó ń ṣọṣẹ́.

Bẹẹ ni wọn kesi ijọba lati bojuto awọn eto aabo to dẹnukọlẹ ni awọn agbeegbe ti awọn adigunjale yii ti n ja ran-in.

Arakunrin Tony, to ni wọn ba ọkọ SUV oun jẹ ni aago meji oru, ti wọn si ṣi bonnet ọkọ, ki wọn to fi ipa ṣi ferese ọkọ, ti wọn si raye wọle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin eyi lo ni wọn yọ engine ọkọ, ina ọkọ, batiri ọkọ, jigi ẹgbẹ ọkọ ko to di wi pe wọn wa ọkọ ti wọn jade, lẹyin ti wọn ti yọ gbogbo ohun ti wọn fẹ́ yọ tan.

Tony ni o le ni ọgbọn iṣẹju ti awọn onisẹ laabi naa fi sọṣẹ ni agbeegbe awọn, ti ko si si oluranlọwọ kankan fun awọn.

Nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa fesi, wọn ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ti awọn si ti bẹrẹ̀ iwadii ni pẹrẹwu lati mu awọn adigunjale naa.