Peer Pressure: Díẹ̀ lára ọ̀nà tí ọ̀rẹ́ rẹ lé gbà bá aayé rẹ jẹ́

  • Busayo James-Olufade
  • Broadcast Journalist, BBC Yoruba
Awọn ọdọ to n mu siga

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Yoruba maa n sọ pe fi ọrẹ rẹ han mi, ki n sọ iru eniyan ti o jẹ.

Asamọ kan lo ni "fi ọrẹ rẹ han mi, ki n sọ iru eniyan ti o jẹ.

Lootọ kuku ni, o ṣeeṣe ki iru ọrẹ ti eniyan n ba a rin o ni ipa lara rẹ nipa ihuwasi tabi oju ti awujọ yoo fi wo o.

Idahun si ibeere yi le jẹ bẹẹni, o si le jẹ bẹẹ kọ. Ṣugbọn, nkan to daju ni pe, eniyan maa n ṣaba ṣe afarawe awọn iwa tawọn eeyan to ba wa ni ayika wa ba n hu.

Ọpọlọpọ igba, onitọun le e ma mọ pe oun n hu iwa bi tawọn eeyan to wa ni ayika rẹ, to si le jẹ pe awọn eniyan miran ni yoo sọ fun pe, "Lagbaja, iwa ti o n hu ko dara to tabi ki lo de to n huwa bii Tamẹdo?".

Bakan naa, eniyan le kọ iwa buruku tabi iwa rere lati ara ọrẹ to ba n ba a rin.

Awọn iwa ti eniyan le kọ lara ọrẹ ree:

Ọti mimu:

Ọti mimu kii ṣe ohun ti ko dara, ṣugbọn amupara ni wahala, nitori pe o le ba ẹya ara kan tabi omiran jẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ṣeeṣe ki o ma mọ bi awọn ọrẹ rẹ ṣe bẹrẹ ọti mimu, ṣugbọn o le deede ri i pe, iwọ naa darapọ mọ wọn, ti ẹ si jọ n lọ sile ọti kiri.

Nigba miran, o ko fẹ fi ara rẹ han bi ẹni ti ko 'ja si' tabi to jẹ òpè nigba ti awọn ọrẹ rẹ ba pe ọ pe ile ọti ya fun faaji.

Ti o ko ba si ko ara rẹ nijanu lori iru ihuwasi bayii, o lee sokunfa iku aitọjọ fun ọ nitori pe aguntan to n ba aja rin, yoo jẹ igbẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọti mimu le fa aisan ọkan, ẹjẹ riru ati itọ ṣuga.

Siga fifa:

Bi ọti mimu ṣe l'ewu fun ilera, naa ni mimu siga tabi oogun oloro miran lewu, gẹgẹ bi awọn onimọ eto ilera ṣe sọ.

O le fa aisan bii ikọ'fe, aisan ọkan, rọpa-rọsẹ ati ju bẹ ẹ lọ.

Ọpọ awọn to n fa siga tabi nkan miran, kọ ọ lati ọwọ ọrẹ wọn, pupọ ninu wọn si maa n fi eyi pamọ fun awọn obi wọn, ki wọn o ma ba a mọ.

Ko si si ọmọde kan to dede ni oun yoo maa fa siga lai jẹ pe o ti fi awọn eeyan kan to n mu siga ni ayika rẹ se awokọse, tabi ki awọn ọrẹ to n ba rin se koriya fun lati se bẹẹ.

Awọn miran ti lẹ ti dan oogun oloro to ti ṣe akoba fun ilera wọn wo.

Awọn ọrẹ rẹ le fi ọna mimu siag ati eegbogi oloro miran han ọ, ti o ba n wa pẹlu wọn nigba gbogbo.

Ounjẹ ajẹju:

Njẹ o ti ẹ mọ pe ajẹju ounjẹ ko dara fun ara rẹ? O le beere lọwọ awọn to sanra asanju.

Diẹ lara awọn to sanra asanju ni kii jẹ ounjẹ ti wọn se nile wọn nikan, awọn kan sanra ju bo ṣe yẹ lọ nitori pe wọn maa n jẹ oriṣiriṣi ounjẹ ti ko ṣara loore lasiko ti wọn ba wa ni awujọ ọrẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn onimọ eto ilera sọ pe ounjẹ ajẹju le fa aarun bi ara asanju, ẹjẹ riru, apọju ọra ninu ara, idiwọ si bi o ṣe n mi, ati oorun sisun.

Ọpọ awọn eeyan to sanra ni wọn maa n jẹun bii ẹnipe wn ko ni jẹ ounjẹ miran mọ, koda, ọpọ ipapanu ti wn jẹ pẹlu awọn ọrẹ gan n dakun ara asanju wọn.

Ewu si wa fun ọ, eyi to lee mu ẹmi rẹ lọ to ba kundun jijẹ ounjẹ tabi ipapanu ni aimọye igba lojumọ nitoripe awọn ọrẹ rẹ n se bẹẹ abi awọn eeyan miran to yi ọ ka.

Ounjẹ ajẹju le fa arun bi ara asanju, ẹjẹ riru, apọju ọra ninu ara, idiwọ si bi o ṣe n mi, ati oorun sisun, gbogbo awọn aisan yii si lo lee sokunfa iku aitọjọfun ọ.

Àkọlé fídíò,

Oúnjẹ níwọ̀nba lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má sanra púpọ̀

Ere idaraya:

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn onimọ ilera sọ pe, ere idaraya dara ni ṣiṣe, ṣugbọn ko wa fun gbogbo eniyan.

Ṣugbọn, ṣe o mọ pe ti o ba ni awọn ọrẹ to maa n ṣe ere idaraya, ko rọrun fun ọ lati mase darapọ mọ wọn, nitori pe yoo wu ọ, ti o ba ri ti wọn n ṣe e.

Kii ṣe gbogbo eniyan ni o darapọ mọ ọrẹ lati ṣe e, ṣugbọn ọpọ yoo ṣe nitori pe wọn ko fẹ ẹ yọ l'ẹgbẹ, ti iru awọn ọrẹ bẹ ba n sọrọ nipa ere idaraya.

Ṣiṣe ere idaraya lọna ti ko tọ le yọri si ifarapa, yiya arọ tabi iku.

Oyun tabi ibalopọ ti ko tọ:

Ti o ba beere lọwọ ọpọlọpọ ọkunrin tabi obinrin to ni ololufẹ pe, ki,ni idi ti wọn fi wa ninu irinajo ifẹ, ọpọlọpọ wọn ni yoo sọ fun ọ pe, awọn n ṣe e nitori pe ọrẹ wọn bi meji tabi mẹta n ṣe bẹẹ.

Ọpọ maa n gbe awọn igbesẹ kan nitori pe wọn ko fẹ ki awọn ọrẹ wọn fi wọn ṣe yẹyẹ.

Iwadii kan ti MI Norton ati awọn akẹẹgbẹ rẹ kan ṣe nilẹ Amerika safihan bi awọn eniyan ṣe maa n ṣe afarawe iwa ti ko dara lara ọrẹ wọn.

Awọn iwa miran ti o tun le kọ lara ọrẹ ni:

Ai tete maa sun lalẹ nitori ẹjọ riro lori ẹrọ ibanissrọ.

Bakan naa lo le ri pe o n nawo ju boṣeyẹ lọ nitori pe o n ṣe afarawe awọn ọrẹ rẹ.