Coronavirus: Ẹ wo ọ̀nà tí àjàkálẹ̀ àrùn gbà mú àyípadà bá ìlànà ìjọ́sìn ní Ṣọ́ọ́ṣì àti Mọ́ṣálásí

Musulumi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ààrùn Coronavirus tí mú ìyípadà bá bí àwọn ènìyàn ṣe n sìn ní ilé ìjọsìn àti mọ́sáláṣi' káàkírí àgbáyé.

Covid-19 ti awọn eniyan mọ si Coronavirus ti mu ayipada ba bi awọn eniyan ṣe n ṣe ẹsin kaakiri ile ijọsin awọn ọmọlẹyin Kristi lagbaye ati mọsalasi.

Awọn ọmọlẹyin Kristi ati musulumi ni Saudi Arabia, Iran, Britain, Palestine, Pakistan, Tajikistan, Singapore ati Ghana ni wọn ti kilọ fun, lati yẹra kuro ni awọn ile ijọsin lati dẹkun itankalẹ aarun naa.

Ọpọlọpọ awọn orilẹede lagbaye lo ti kilọ fawọn eniyan lati sọra fun bi wọn ṣe n kini ati bi wọn ṣe n jẹun lasiko yii.

Saudi Arabia gbegile Umurah fọdun 2020:

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba ilẹ Saudi Arabia ti gbekile Umurah fun saa yii lọna ati gbogun ti arun Coronavirus.

Umarah ni wọn n pe ni Hajj kekere ti awọn eniyan ma n wa fun to yatọ si irinajọ lọ si Mecca ti o ma n waye lọdọọdun.

Agbẹnusọ fun minisita fun ọrọ abẹle lorilẹede naa ni, awọn n gbe igbeṣẹ naa lati ṣe atilẹyin fun igbesẹ ijba ilẹ naa ati ti agbaye lati wa ojutu si aarun naa.

Nibayii eniyan meji lo ti lugbadi arun naa ni Saudi Arabia.

Palestine wọgile irinajo afẹ sibudo ti wọn bi Jesu si:

Oríṣun àwòrán, AFP

Ile ijọsin to wa ni Bethlehemu ti ọgọọrọ eniyan ma n lọ lọdọọdun, ti awọn ọmọlẹyin Kristi ti ma n ṣe ọjọ ibi Kristi ni wọn ti ti pa bayii, lati koju arun Coronavirus.

Eyi ko ṣẹyin bi eniyan mẹrin ṣe lugbadi arun naa lorilẹede naa.

Ijọba Palestine ti paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ile ijọsin, mọsalasi ati ile itura lọna ati dena awọn arinrinajo, ki wọn mase wọ orilẹede naa.

Iran fofin de lilọ mọsalasi fun irun janmọ lọjọ Jimọ:

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Iran ti wọgile lilọ si mọsalasi ni Ọjọ Eti lati lọ gbadura lọna ati dena aarun naa.

Kaakiri awọn ilu nla to wa lorilẹede ni wọn ti ti mọsalasi ni Ọjọ Eti.

Aarẹ ilẹ Iran ni aarun naa n ṣe eniyan bi ala ni ati wi pe eniyan mejilelaadọrun lo ti ku nitori Coronavirus.

Tajiskistan ni ki awọn muslumi gbadura ni ile wọn:

Tajiskistan ti ko i tii ni aarun Coronavirus ti kilọ fun awọn eniyan wọn lati gbadura nile.

Orilẹede to ni awọn eniyan to le ni miliọnu mẹsan ni ọpọlọpọ awọn eniyan to jẹ ẹlẹsin musulumi.

Bakan naa ni wọn ti ti ibode wọn pẹlu China ati Afganistan, bẹẹ ni wọn ti kọ lati jẹ ki awọn ara ilẹ South Korea, Iran tabi Italy wọ orilẹede wọn.

Kò sí Ounjẹ Alẹ Oluwa mọ ni Ile Ijọsin Aguda ni Ilẹ Gẹẹsi

Ile Ijọsin Aguda ti kilọ fun awọn ọmọ ijọ wọn lati sọra fun pipin Ounjẹ Alẹ Oluwa ni ile ijọsin nitori ewu itankalẹ aarun Coronavirus.

Adari Ijọ Ajuda ni ile Gẹẹsi ti fi atẹjade ati eto lede bi wọn yoo ṣe ma a ṣe ẹsin lorilẹede naa.

Bakan naa ni wọn paṣẹ fun ẹnikẹni to ba wukọ abi to n sin lati joko sile wọn, ki wọn ma si gba aago ti wọn fi n pin ounjẹ alẹ oluwa.

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn musulumi nilẹ Gẹẹsi naa paṣẹ fun awọn musulumi tẹle ofin ijọba lori ajakalẹ aarun Coronavirus ati ọna ati dena rẹ.

Oye awọn ti aarun naa ti ran ni Ilẹ Gẹẹsi ti jẹ ọgọrun ati mejidinlogun (116).