Oyo Reistgrar: Ilé ẹjọ jú akọwe kọotù tẹ́lẹ̀ri sẹwọ̀n ọdun márùn fu ẹsun olè jíjà

Mutiat

Oríṣun àwòrán, EFCC

Àkọlé àwòrán,

Ilé ẹjọ jú akọwe kọotù tẹ́lẹ̀ri sẹwọ̀n ọdun márùn

Ajọ to n ri si ìgbógun ti ìwà àjẹbánu lórilẹ̀-èdè Naijiria EFCC ẹka ti Ibadan ti gba ri idajọ gba nile ẹjọ pe ki ìgbákeji akọwé kọọtu, ilé ẹjọ gíga ìpińlẹ̀ Oyo, Mutiat Omobola Adio lọ si ẹwọn ọdun márun.

Adajọ Muniru Olagunju ni Mutiat jẹbi ẹsùn oní kókó kan, ti EFCC fi kàn-an.

Wọ́n fi ẹsùn kan Mutiat pe o ji mílíọnu mẹ́tàlélogun dín díẹ̀ ni ilé ifowopamọ GuarantyTrust, ẹ̀sẹ̀ ti o lòdi si òfin ìpínlẹ̀ Oyo.

O jẹ̀bi ẹsùn pé o ń lo ọfisi rẹ ni ilodi si ofin làti ja olè.

Adajọ ni oṣe eleyi lásìkò to jẹ akọwé ẹgbẹ̀ alájẹṣẹku ẹká idájọ nipinlẹ Oyo nípa fifi owó kún owó ti àwọn ènìyàn ba yá ninu ẹgbẹ́ láti ilé ifowopamọ GTB ti o si n sọ èlé ori rẹ di ti ẹ.

Adio ni o sába maan ṣe kòkári ẹyáwó ti o si ti mójú to bi mílíọnu lọ́na ààdọrun mílíọn Naira.

Inú oṣù kẹrin ọdun 2017 ní EFCC kọ́kọ́ wọ́ọ lọ si ilé ẹjọ ti o si ni òun ko jẹ̀bi ẹsun náà, lẹ́yìn ti àwọn olùfisùn pèsè ẹlẹri márùn ọtọọtọ, sùgbọ́n ènìyàn méji pere ni adájọ pè.

Nínú ìdájọ rẹ̀, lẹ́yìn gbogbo atótónu àwọn ìhà méjèèjì, adájọ Olagunju sọ pe ó jẹ̀bi ẹsùn àti pe ki o lọ ṣe isẹ́ aṣekara fun ọdun márùn, lai si ààyé fun owó ìtanran.

Bákan náà ni ilé ẹjọ ni ki o dá ogún mílíọnu pada si ilé ifowopamọ GTB nibi ti o ti ji owó.