Kemi Afolabi di màmá olóyè nínú ẹ̀sìn, oyè ìmọ́lẹ̀ Àdínnì ni wọ́n fi jẹ

Kemi Afolabi Adesipe

Oríṣun àwòrán, Instagram/Kemi Afolabi

Gbaju-gbaja oṣerebinrin Yoruba, Kemi Afolabi Adesipe ti di ọkan lara awọn oloye ẹsin Islam.

Oye 'Imọlẹ Adinni' ni oṣere naa to tun jẹ Alhaja jẹ.

Arẹwa oṣere ninu ọrọ kan to kọ si oju ewe ayelujara Instagram rẹ pẹlu awọn aworan to jẹ oju ni gbese sọ pe ijọ ẹsin Islam, Hizbullahi International Prayer Outreach Ministry, lo fi oun jẹ oye naa l'ọjọ Aiku, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2020.

Kemi sọ pe nkan to ju ọla lọ ni bi wọn ṣe fi oun jẹ oye naa, nipa dida oun mọ bi imọlẹ ati olutọnisọna ni aye ode oni.

"Wọn ti gbe ojuṣe le mi lọwọ lati jẹ awokọṣe fun ọpọlọpọ eniyan, mo ṣi ṣe ileri pe maa ṣe ojuṣe mi pẹlu ẹmi ifọkansin si Allah, bi Allah ba fẹ."