Coronavirus: Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Nàìjíríà kó igbá wọlé l'Abuja nítorí coronavirus

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Nàìjíríà kó igbá wọlé l'Abuja nítorí coronavirus

Ile igbimọ aṣofin Naijiria ti kogba wọle nilu Abuja to jẹ́ olu ilu Naijiria nitori coronavirus to gbode kan.

Alhaji Ahmad Lawan to jẹ abẹnugan ile igbimọ aṣofin ni Abuja lo ṣiṣọ loju ipinnu gbogbo ọmọ ile yii nilu Abuja lonii.

O ni igbesẹ yii di dandan lati gbe lasiko yii lataari aarun coronavirus to ti le ni ogoji eeyan to ti lugbadi ẹ ni Naijiria bayii.

O rọ awọn eniyan Naijiria lati gbọran si aṣẹ ajọ NCDC lẹnu ki onikaluku yan imọtoto laayo bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNikesuliat: Ọ̀dọ́mọdébìnrin akéwì tó n fi ẹ̀ṣà kìlọ̀ ìwá lásìkò yìí

Èrò wìtì-wìtì lọ́jàa Dugbẹ, Bodija, Orita-Challenge láì náání Corona Virus ní Ibadan

Corona Virus in Nigeria: Buhari: Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ní kí àwọn òṣìṣẹ́ grade 1 sí 12 jókòó sílé

Àkọlé àwòrán Buhari: Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ní kí àwọn òṣìṣẹ́ grade 1 sí 12 jókòó sílé

Aarun COVID-19 ti di tọrọfọnkale bẹẹ sini o ti lu ọpọ ẹmi pa, ṣugbọn bi aarun yii ṣe lewu to, ọpọlọpọ awọn eeyan ni ko tii fi bẹẹ mu imọtoto ara ẹni ati yiyago fun ọpọ ero nigboro lọkunkundun.Abẹwo ti ikọ iroyin BBC ṣe si igboro ilu Ibadan fi han wi pe ewu n bẹ loko longẹ Wo bí àwọn ará Ibadan ṣe ń ṣe lásìkò Corona Virus yìí

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo itan omi gbigbona ati tutu ni Ikọgosi Ekiti

Aṣẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ pa lori ẹdinku ti o yẹ ki o ba iye ero ti awọn ọlọkọ ati ọlọkada n gbe ko tii walẹ.Alaye awọn ọlọkada, oni-Maruwa ati awakọ ero ni wi pe awọn to n gba owo lọwọ wọn fun ijọba (park managers) gbudọ kọkọ din iye ti wọn n gba lọwọ wọn ku na ki ẹdinku to le ba iye ero ti wọn n gbe.

Wọn tẹsiwaju wi pe lai ṣe eyii, ko ni rọrun fun awakọ ati ọlọkada ti o ba tẹle aṣẹ ijọba lati ri owo mu dele lẹyin ti o ba ṣiwọ iṣẹ tan.

Àkọlé àwòrán wọn to n to lọwọọwọ lati wọ inu ile ifowopamọ naa ko ni onka.

Lorii sisun mẹyin funra ẹni lawujọ:

Aṣẹ naa ko tii di itẹwọgba nitori ọgọọrọ awọn eeyan lo to si ẹnu awọn ẹrọ to n pọ ọwọ lọwurọ oni lai sun fun ara awọn.

Awọn to n to lọwọọwọ lati wọ inu ile ifowopamọ naa ko ni onka.

Bo tilẹ jẹ wi pe gbogbo awọn onibara ni awọn oṣiṣẹ ile ifowopamọ n ṣe ayẹwo fun ki wọn to wọle, bi awọn ẹniyan wọnyii ṣe sunmọ ara wọn pẹkipẹki gan an lo n kọnilominu.

Karakata ṣi n lọ ni awọn ọja bii Dugbẹ, Bodija, Orita-Challenge ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ati ontaja ati onraja lo n fi ara nu ara wọn lọwọ ti ẹnikẹni ko si bikita.Alaye wọn ni wipe bi ọja ba di titipa niori aarun Corona, afaimọ ki ẹbi ma lu awọn eeyan pa sinu ile.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn fíìmì òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú

Ìjọba àpapọ̀ ní kí àwọn òṣìṣẹ́ grade 1 sí 12 jókòó sílé nítorí Coronavirus

Buhari: Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ní kí àwọn òṣìṣẹ́ grade 1 sí 12 jókòó sílé

Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ijọba tí wọn wa ni ipele ikinni si ikejila lati ma wa si ibi iṣẹ mọ.

Adari awọn oṣiṣẹ ijọba, Dokita Folasade Yemi-Esan lo fi atẹjade yii ṣọwọ si awọn oṣiṣẹ ijọba lọna ati dena itankalẹ arun Coronavirus.

Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ogójì ènìyàn ló ti ní àrùn Coronavirus lórílẹ̀-èdè Nàíjíríà, tí ó sì ti pa ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn ní àgbáyé.

Yemi-Esan ninu ọrọ rẹ sọ wi pe eto ilẹra awọn oṣiṣẹ ijọba jẹ awọn logun nitori ọmọ Niajiria rere ni awọn naa.

O rọ awọn oṣiṣẹ ijọba lati tẹlẹ aṣẹ awọn eto ilera lori imọtoto ki arun naa ba le tete ka kuro nilẹ.

Yemi-Esan ni awọn oṣiṣẹ ipele ikejila silẹ gbọdọ ṣiṣẹ lati ile bẹrẹ ni Ọjọ Iṣẹgun, Ọjọ Kẹrinlelogun, Osu Kẹta, ni ọdun 2020 titi akoko ti ajakalẹ arun naa yoo fi ka kuro nilẹ.

Ijọba wa paṣẹ fun awọn ọga agba iṣẹ ti yoo ma a lọ ileeṣẹ ki wọn ri wi pe awọn ko gba alejo pupọ julọ.

Bakan naa ni wọn paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ti wọn ti lọ si orilẹ-ede ti arun Coronavirus ti peleke, abi ti wọn ba ti ni ifọwọwẹwọ pẹlu awọn ti o ba ti de lati oke okun lati se ara wọn mọ ile.

Awọn ti wọn ba si ti n ri awọn ami to dabi ẹni pe wọn ni arun Coronavirus yii, wọn gbọdọ pe ileeṣẹ to n risi ajakalẹ arun (NCDC) lori nọmba 0800970000-10.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus in Nigeria: Ẹ wo àǹfààní tó wà nínú àrùn Coronavirus