CovidNGR: Ìjọba fẹ́ f'òfin de irina ọkọ̀ akèrò jakejado Nàìjíríà láti dènà àrùn nípasẹ̀ wọléwọ̀de

Image copyright Getty Images

Ni itẹsiwaju ọna ati dẹkun ajakalẹ aisan Coronavirus ni Naijiria,ijọba apapọ ti kede pe awọn yoo gbe igbesẹ lati fofin de irinajo laarin ipinlẹ si ipinlẹ.

Nipa igbesẹ naa, o ṣeeṣe ki wọn ti gbogbo awọn ibudo iwọkọ ni Naijiria pa.

Oluranlọwọ si aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin ayelujara Bashir Ahmad lo fi ọrọ yi to ni Minisita feto iroyin Lai Mohammed sọ sita loju opo Twitter rẹ lọjọbọ

Ṣaaju asiko yi ni ijọba ti fofin de irinajo lawọn wọ Naijiria lati awọn ilẹ okere kan ti wọn si tun ti awọn ibode Naijiria naa pa.

Ko ti si alaye ẹkunrẹrẹ lori bi igbesẹ yi yoo ti ṣe waye ṣugbọn awọn ijọba ipinlẹ kan ti n gbero igbesẹ yi ti awọn kan bi Kano si ti ni ko saye iwọlewọde ni awọn ibode wọn mọ.

Minisita Lai Mohammed lasiko to n fi ọrọ yi to awọn akọroyin leti ni lọwọlọwọ bayi ni Naijiria, ijọba ti fofin de irina oju irin reluwe jakejado Naijiria.

Aàrùn Coronavirus kìí ṣe ìdájọ́ ikú- Ọmọ Naijiria tó ní aàrùn náà

Ọmọ Naijiria kan to jẹ nọọsi nilu New York lorilẹ-ede Amẹrika, Chi Onu, ti sọ pe aarun Coronavirus kii ṣe idajọ iku.

O ṣalaye pe oun lugbadi aarun naa lẹnu iṣẹ nọọsi lẹyin ti oun ṣetọju ẹnikan to ni aarun naa lara, leyi to mu ko yara rẹ sọtọ fun itọju.

Onu sọ pe "Ọjọ kẹtala ree ti mo ti mọ pe mo ni Coronavirus ṣugbọn ko si apẹrẹ aarun na lara mi ati ẹbi mi."

Afikun nipa aarun Coronavirus
Afikun nipa aarun Coronavirus

Nọọsi Onu ni: "Mo lọkọ, mo si ni ọmọ meji ti a jọ n gbe papọ, a jọ n ṣe ohun gbogbo papọ bi ẹbi kan ni ti mi o si mọ pe mo ti ni arun Coronavirus.

Sibẹ, ko si ẹnikan ninu wa to n fi apẹrẹ aarun naa han."

Nọọsi naa tẹsiwaju pe "Aarun Coronavirus kii ṣe idajọ iku, nitori emi ati ẹbi mi wa lalaafia, bo tilẹ jẹ pe mo ti fara kaasa aarun yii."

O ṣalaye pe awọn to ti ni ailera tẹlẹ ni arun naa n pa lara ju, bi ẹni to ni aisan jẹjẹrẹ tabi awọn ti wọn ni arun ẹdọforo, ati bẹbẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Nọọsi naa wa gba awọn eeyan niyanju lati ma faaye gba ibẹru, ṣugbọn ki wọn ma jẹ ounjẹ gidi ati eso to ni awọn eroja aṣaraloore bi ẹfọ, ọsan ati gbogbo eso ti ọwọ wọn ba le tẹ.

O ni ayẹwo ti fi han pe ẹdọforo ati aya oun wa ni alaaifa, ati pe aarun naa ko ti raye wọ ibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Gbogbo igbá ti ṣófo láwọn ilé ìtajà káàkiri London

Nọọsi ọhun pari ọrọ rẹ pẹlu imọran pe aarun Coronavirus kiii ṣe ọrọ ti eeyan n fọwọ yẹpẹrẹ mu, nitori naa ki awọn eeyan mu ọrọ ilera ara wọn ni pataki.

O ni oun nireti pe aarun naa yoo fi ara oun silẹ laipẹ ti oun yoo si pada sẹnu iṣẹ gẹgẹ bi adoola ẹmi.

Èsì àyẹ̀wò aàrùn Coronavirus tí Gomina ìpínlẹ̀ Ondo ṣe ti jáde

Coronavirus: Èsì àyẹ̀wò aàrùn Coronavirus tí Gomina ìpínlẹ̀ Ondo ṣe ti jáde

Gomina ìpínlẹ̀ Ondo, Arakunrin Akeredolu kò ní aàrùn Coronavirus, o ti n fọpẹ́ fún Oluwa.

akeredolu Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Akeredolu: Orí kó mi yọ!

Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu ti fi esi ayẹwo aarun Coronavirus to ṣe sita lede.

Akeredolu ni oju opo ikansiraẹni Twitter rẹ sọ wi pe Kọmisọnna eto ilẹra nipinlẹ Ondo lo fi esi ayẹwo naa sita pe oun ko ni aarun Coronavirus.

O dupe lọwọ Olorun fun aṣeyọri esi ayẹwọ naa, o si gbadura fun awọn to ti ni aarun naa pe ki Olorun fun wọn ni iwosan pipe.

Gomina ipinlẹ Ondo naa wa parọwa si awọn araalu lati kiyesi eto ilakalẹ ọna lati dena itankalẹ aarun Coronavirus.

Akeredolu fikun un wi pe awọn n ṣe ohun gbogbo ti awọn nilo lati dena ki aarun naa ma baa tan kalẹ ni ipinlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌgbẹ́tì: Òkè Ìyámàpó ló gba wàá sílẹ̀ lọ́wọ́ ogun

Wọ́n fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan ònídìrí tó kọ̀ láti yara rẹ̀ sọ́tọ̀ nítorí COVID 19

Coronavirus: Wọ́n fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan ònídìrí tó kọ̀ láti yara rẹ̀ sọ́tọ̀ nítorí COVID 19

Ọlọpaa South Africa ti Ladysmith pẹ̀lú ẹ̀sùn yìí nítorí o kọ̀ láti yara ẹ sọtọ bó ṣe yẹ nitori coronavirus.

south Africa Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan South Africa n palẹmọ de konile-o-gbele ọlọsẹ mẹta tijọba wọn kede

Gbajugbaja Onidiri kan ni orilẹ-ede South Africa ni wọn ti fi ẹsun ipaniyan kan.

Awọn agbofinro ni o kọti ọgbọnyin si aṣẹ pe ko duro sile ko fi ara rẹ pamọ fun ọjọ mẹrinla bi o ti yẹ lẹyin to ti ni aarun coronavirus.

Ẹni ọdun mejilelaadọta aṣerunloge ọmọ South Africa naa ni ṣọọbu rẹ wa ni ilu Ladysmith ni o lugbadi aarun coronavirus ti wọn si da duro sile iwosan fun itọju ko to sa kuro nibẹ.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹta yii ni ọwọ awọn agbofinro tẹẹ nibi to ti n ṣe irun fawọn onibara rẹ.

Awọn agbofinro ni onidiri yii lati ẹkun KwaZulu-Natal ti ba awọn eniyan mẹtadinlọgbọn ṣe bayii ti wọn ko si tii mọ boya awọn eeyan naa ti ni coronavirus lati ara rẹ.

Wọn ti gbe aṣerunloge yii pada lọ sile iwosan fun itọju pipe ati abojuto.

Ṣaaju ni asiko yii ni awọn eniyan ti n sare ra nkan sile nitori ikede konile-o-gbele ọlọsẹ mẹta tijọba kede rẹ ni South Africa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Fífi nkan bó ìmu nìkan kò le dènà kíkó coronavirus

Ha! Mo ṣe ìpàdé pẹ̀lú ẹni tó ní Coronavirus- Gomina Akeredolu

Rotimi Akeredolu: Mo tí ṣetán láti ṣe àyẹ̀wò bóyá mo ní Coronavirus

Ọpọlọpọ Gomina lorilẹ-ede Naijiria lo ti jade lati lọ ṣe ayẹwo bóyá wọ́n ní aàrùn Coronavirus láti ìgbà tí àjàkálẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀.

akeredolu Image copyright @Akeredolu
Àkọlé àwòrán Mo tí ṣetán láti ṣe àyẹ̀wò bóyá mo ní Coronavirus

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti sọ wi pe oun ti jọwọ ara ohun lati ṣe ayẹwọ fun arun Coronavirus.

Eyi ko ṣẹyin awọn eniyan to bu ẹnu atẹ lu Gomina naa pẹ ko lọ ṣe ayẹwo ara rẹ nitori o ṣe ipade pọ pẹlu ẹni ti ileeṣẹ eto ilera sọ wi pe o ni arun Coronavirus.

Akeredolu ninu atẹjade lo fi lede sọ wi pe, oun gbe igbesẹ naa nitori ẹni ti oun ba ṣe ipade ti ni arun Coronavirus.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn Obinrin Dahomey: Awọn obinrin ilẹ Afirika ti wọn yii itan pada re e

O fikun un wi pe oun yoo jẹ ki awọn eniyan mọ esi ayẹwo Coronavirus naa laipẹ.

Gomina ipinlẹ Ondo wa ni ipade ni ilu Abuja pẹlu awọn gomina to wa lorilẹ-ede Naijiria.

Nibayii, ọkan lara awọn gomina naa ti ni aarun Coronavirus naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus in Nigeria: Ẹ wo àǹfààní tó wà nínú àrùn Coronavirus

Gomina ipinlẹ Ekiti ati ti ipinlẹ Niger to wa ni ibi ipade naa ti se ara wọn mọ ile bayii, ti wọn si ti lọ ṣe ayẹwo ara wọn.

Image copyright @akeredolu
Àkọlé àwòrán Mo ṣe ìpàdé pẹ̀lú ẹni tó ní Coronavirus

Amọ awọn eniyan sọ wi pe Gomina Akeredolu kọ lati se ara rẹ mọle ti o si ti ṣe ipade pẹlu Kọmisọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Adie Undie ni ọjọru, ọsẹ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn fíìmì òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú