Yolllywood: Ọlọ́run ló kọọ pé àwọn ọmọ mi yóò ṣiṣẹ tíátà, èmi kọ lo kàn-án nípa fún wọn - Ọga Bello

Oga Bello

Oríṣun àwòrán, Oga Bello

Àkọlé àwòrán,

Ọlọ́run ló kọọ pé àwọn ọmọ mi yóò ṣiṣẹ tíátà, èmi kọ lo kàn-án nípa fún wọn - Ọga Bello

Àgbà osere tíátà Adebayo Salami, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ si ọga Bello, tí sọ ìhà tó kọ sí bí àwọn ọmọ bibi inú rẹ, se ń ba se ere tíátà. Ọga Bello, lásìkò to ń kopa lórí eto kan pẹlu BBC Yoruba ni ọsan ọjọ́ Iṣẹgun, sísọ lójú rẹ pé,

Ọlọ́run ló kọ ọ pé àwọn ọmọ òun yóò ṣe ère orí itage jẹun nitori pe, fúnra wọn ní wọn finnu-findọ pinnu láti máa ṣíṣẹ ère orí itage, òun sì kó lọ kàn-án nípa fún wọn.

Àkọlé fídíò,

Lockdown the world: Awọn ọmọ Nàìjíríà káàkiri àgbáyé sọ ìrírí lábẹ́ àṣẹ kónílé-ó-gbélé

O ni: "mo máa ń rí àwọn ọmọ mi bíi osere akẹẹgbẹ mi lásìkò tí a bá ń ṣíṣẹ sinima lọ́wọ́, gbogbo ohun tí wọn ba si ṣe fún mi lásìkò náà, kii dùn mi rárá.

"Ọjọ́ kan tiẹ̀ wà, tí èmi ati Femi jọ kopa ninu ere, tó si ṣe ọga fún mi, tó ń sọ̀rọ̀ si mi, lẹ́yìn ta parí ère tán, lo padà wá bẹ mi, pé kí n má bínú àmọ́ èyí kò ní ìtumọ̀ kankan sí mi."

Ọga Bello, lásìkò to ń koro ojú sì bí àwọn ère itage ni èdè Yorùbá kan ṣe ń kùn fún ọpọ èdè gẹ̀ẹ́sì, ó ní, èyí dá lórí irú ipò tí èèyàn kan bá fẹ́ ṣe nínú eré.

Amọ́ ó tún woye pe, ìwọ̀nba ni èdè gẹ̀ẹ́sì gbọdọ mọ nínú eré Yoruba.Ọga Bello tún woye pe, nínú sinima ti orin bá ti ń bo ere mọlẹ, a jẹ pé Olootu ere náà kii ṣe akọsẹ-mọṣẹ osere tíátà ni.

Agba ọjẹ nínú isẹ tíátà náà tún ṣiṣọ lójú rẹ pé, olóògbé Ojo Ladipo, ti ọpọ èèyàn mọ si bàbá Mero, ní ọga to kọ òun ni iṣẹ tíátà, òun si lo sọ òun ni inagijẹ Ọga Bello nínú eré tíátà, láti ọdún 1973.

Toyin tí ẹ mọ̀ tẹ́lẹ̀ yàtọ̀ sí èyí tó wà lójú ọpọ́n báyìí-Toyin Abraham

Yoruba Film: Toyin Abraham ní ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí òun fẹ́ ti mú àyípadà rere bá ayé òun

Sáájú ni o ti gbé e sí orí àtẹ̀jísẹ́ instagram rẹ̀ pé "ọmọ ọlọ́jọ́ ìbí, Jésù mo dúpẹ́ fún ìfẹ́ rẹ̀. Mi ò ní ya aláìmoore.

Toyin Abraham ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham

Gbajúmò óṣeré tíátà lóbìnrin, Toyin Abraham tí kéde pé, ilé ọkọ tí òun wa ti mú àyípadà rere bá igbe ayé òun.Toyin, lásìkò to ń sọ̀rọ̀ lórí eto orí telifisan kan n'ilu Eko ṣàlàyé pé, ọkọ òun, tíì ṣe ẹni tó lọgbọn nínú ìwà àti ọpọlọ, tí mú àyípadà réré bá igbe ayé òun, yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀.

"Koda, ìrírí tó dára julọ fún ẹ̀dá ni ìgbéyàwó jẹ nítorí ó tí yí idamọ mi padà. Mo ti di 'Mummy Ire', ìgbéyàwó mi sì ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí mú àyípadà bá mi, mo sì ti kúrò ní Toyin tí àwọn èèyàn mọ tẹ́lẹ̀."

Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham

Bẹẹ bá gbàgbé, ọjọ́ kẹrin oṣù keje ọdún 2019 ni Toyin Abraham àti ọkọ̀ rẹ, Kolawole Ajeyemi ṣe ayẹyẹ ìdána n'ilu Ibadan, tí ọba òkè si fi ọmọkùnrin kan lanti lanti tá wọn lọrẹ, ti orúkọ rẹ ń jẹ Ire.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí eto iranwọ to ṣe lásìkò igbele Coronavirus yìí, Toyin Abraham ni òun ti pín owó àti èròjà oúnjẹ fún àwọn olólùfẹ́ òun ti oun mọ káàkiri ìlú Èkó, ibadan, Ogbomoso, Ilorin, Kano àti ní Ìpínlẹ̀ Ogun, ní ìwọ̀nba tí

agbára òun ka.

Toyin sọ síwájú pé, òun rí pe Ọlọ́run ló ń fi agbára rẹ hàn wá nípa àrùn Covid-19 yìí, nítorí ohun gbogbo kò leè rí bíi ti àtẹ̀yìnwá mọ, lẹ́yìn ti àrùn náà bá kasẹ nilẹ.

Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham

"Lásìkò yìí, ọna bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wá kò ṣe ní kú là ń ṣàn, bí a ṣe ye là ń wá, a kò lè owó mọ rárá àbí bá ti tà sinima wá, kódà, èmi àti ọkọ mi kan gbé mọto wa kalẹ ni, lai le lọ síbi kankan, ẹ rí pé èyí lágbára gan ni."

Wàyí o, ní agbo àwọn Òṣeré tíátà ni ọsẹ yìí, kò fẹẹ sì bẹbẹ tí wọn ṣe nítorí aawẹ Ramadan tó wọlé de.

Àmọ́ àwọn óṣeré yìí kan ń kí àwọn olólùfẹ́ wọn kú oṣù Alapọnle tó wọlé de ni.

Afikun nipa aarun Coronavirus
Banner

Yewande bí'mọ tuntun jòjòló, Mercy Aigbe pàdánù èèyàn rẹ̀, Toyin Abraham fèsì lórí aṣoju NCDC

Awon osere tiata
Àkọlé àwòrán,

Yewande bi'mọ tuntun jòjòló, Mercy pàdánù èèyàn rẹ, Toyin Abraham fèsì lórí ìi asoju NCDC

Toyin Abraham

Gẹ́gẹ́ bi ilé iṣẹ́ BBC News Yoruba lọ́jọọ́jọ́ Jímọ ni a tún mú àwọn ǹkan ti o ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn òsèrè Nollywood Naijiria.

Bótilẹ̀ jẹ́ pé ààrun coronavirus ń ṣe àwọn ènìyàn mọ́lé síbẹ̀ kò di àwọn òṣèré tíátà dúro láti ṣe tíwọn.

Toyin Abraham ní ìròyìn òfégè pé, òun ti di asojú àjọ to n gbógun ti ààrùn Corornavirus ní Naijiria (NCDC), Toyin Abrahim ni ìròyìn òfégè ní àti pé an fi kú pé, òun gba ipo akẹgbẹ́ òun kan láti di aṣojú àjọ NCDC ni.

Àkọlé fídíò,

libya

O ní irú èrò báyìí ni o mú kí òun kọ irú ọ̀rọ̀ yìí si ta. Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ̀ "Èmi kìí ṣe asoju àjọ NCDC, mí kò si nífẹ̀ẹ́ si irú àláye ti wọ́n ba mi fi síta yìí pé mó fi ẹrú gbà ìbùkùn lọ́wọ́ akẹgbẹ́ mí"

Bí ọ̀rs se ri ni pé, mó wà lára àwọn to ṣe ìpolongo lòdì sí Covid -19 mo si fara han nínú fọ́nran náà, sùgbọ́n ó ṣe pàtàkì ki a má fa ẹnìkàn wále nítori ire ti yín.

Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, Toyin?instagram

Àkọlé àwòrán,

Yewande bi'mọ tuntun jòjòló, Mercy pàdánù èèyàn rẹ, Toyin Abraham fèsì lórí ìi asoju NCDC

Mercy Aigbe

Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Mercy/instagram

Àkọlé àwòrán,

Yewande bi'mọ tuntun jòjòló, Mercy pàdánù èèyàn rẹ, Toyin Abraham fèsì lórí ìi asoju NCDC

Nínú ọ̀sẹ̀ yìí bákan náà ni Mercy Aigbe gbe sọ́rí ojú òpó Instagram rẹ pé, "ọjọ́ oní ni o burú jùlọ ní ayé mí, mò rò pé mo le gbe àgbélébu gbogbo ǹkan ti aye ba jù si mi ni sùgbọ́n ko si ǹkan ti o ṣẹll si mi yìí mí o múra sílẹ̀ fún"

Mercy Aigbe ni ọṣẹ kan sosọ yìí jẹ́ eyi to buru jù fun irú ìpinyà yìí òjijì.

"mo ro pé mó n lá àlákálàá ni, mo sì ń ròó pe èníkan yoo ji mi lójú orun.

Láti ilé ìwòsàn ni mo ti n bẹ̀bẹ̀ ki dókítà ṣe ǹkan ti o le ṣe titi a fi dé ilé igbóku sí, pẹlu ìgbàgbọ́ pé, òó tilẹ̀ gbé apá rẹ.

Mo gbàdura titi pẹlú ìgbàgbọ́ pé iṣẹ́ ìyanu ìkẹyin le ṣẹlẹ̀

"Títí di olwúrọ̀ yìí mo si n gbàgbọ́ pe wọ́n o pè mi láti ilé igbóku pamọ́ sí pe o tilẹ̀ sín"

Omowumi Ajiboye

Osere tiata Wumi

Oríṣun àwòrán, Wumi/instagram

Àkọlé àwòrán,

Yewande bi'mọ tuntun jòjòló, Mercy pàdánù èèyàn rẹ, Toyin Abraham fèsì lórí ìi asoju NCDC

Lágbo òṣèré bákan náà lọ́sẹ̀ yìí Omowumi Ajiboye aya Segun Ogungbe náà se ọjọ ibí ti ọ̀pọ̀ awọn akẹ́gbẹ́ rẹ̀ nínú eré tíatia si báa dáwọ idún pẹ̀lú àdúra lọ́tun lósì.

Sáájú ní ó ti gbé si orí àtẹjísẹ́ instagram rẹ pé " ọmọ ọlọjọ́ ìbí, Jesu mo dúpẹ́ fun ifẹ́ rẹ. Mí o ni ya aláìmoore'

Yewande Adekoya Abiodun

Yewande

Oríṣun àwòrán, Yewande/Instagram

Àkọlé àwòrán,

Yewande bi'mọ tuntun jòjòló, Mercy pàdánù èèyàn rẹ, Toyin Abraham fèsì lórí ìi asoju NCDC

Ayò abara tíntín, lọ́nii gán ni ọmọ túntun jòjòló tún wọ agbo àwọn òṣèré tíátà nígbà ti Yewande gbe si ojú òpó instagram rẹ pe, 'Káàbọ̀ sínú ayé wa, ọmọ ọba, ifẹ́ mi.

igbé aye wa ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ papọ̀ ni, o ti di ara wa bayìí ọmọ mi jòjòló.

Àwọn òṣèré tíátà jákèjádò ni wan ti n ki ìyá àbúrò tuntun ku ewu.