Sanusi Lamido Sanusi: Ashraf, ọmọ Lamido Sanusi ní ìṣọ̀kan ṣì wà nínú ẹbi Emir àná náà pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n là kọjá

Sanusi Lamido Sanusi

Oríṣun àwòrán, Governor kaduna

Laipẹ yii ni iroyin kan wọ ilu ti gbogbo ilu si mi titi.

Iroyin naa ni ti irọloye Emir ti ilu Kano, Sanusi Lamido ti ijọba ipinlẹ Kano kede lẹyin ọpọlọpọ itaporogan pẹlu gomina ipinlẹ naa, Abdullahi Ganduje.

Amọṣa lọwọ yii iroyin ayọ ti wọle tọ gomina tẹlẹ fun banki apapọ orilẹede Naijiria ọhun pẹlu ọkan lara awọn iyawo rẹ, Saadatu to bi ọmọ tuntun bayii.

Ọkan lara awọn ọmọ ọkunrin Emir tẹlẹ fun ilu Kano naa, Ashraf to fi idi ibi naa mulẹ ṣalaye pe ọmọbinrin ni Mallam Sanusi Lamido Sanusi bi.

O fi kun un pe iyawo Sanusi Lamido keji torukọ rẹ n jẹ (Goggo) Mamie lo bẹ Emir ana naa pe ko sọ ọmọ ọhun ni orukọ iyawo rẹ akọkọ, iyẹn Yaya (Giwa) ti wọn ni o tọju Saadatu`nigba to wa ninu oyun.

Halimatu Saadiyya ni o kede pe wọn sọ ọmọ naa.

Ọba Gbadamọsi: Olúwòó, ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria fi ìkíni ránṣẹ́ si Ọlọ́fà fún ayẹyẹ ọdún mẹwàá lórí oyè

Oríṣun àwòrán, Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ọba tó ṣe fi yangàn láàrín ọba Nàìjíríà ni Ọlọ́fà ìlú Offa-Oluwo

Oluwo ilu Iwo Oba Abdulrasheed Akanbi ti darapọ mọ awọn ọmọ Yoruba to n fi ikini ransẹ si Ọlọfa ilu Offa Oba Mufutau Gbadamosi Oloyede to pe ọdun mẹwa lori apere.

Ninu ọrọ to fi ransẹ si ileesẹ BBC Yoruba, Oba Abdulrasheed sapejuwe Ọlọfa gẹgẹ bi ọba to se fi yangan lawujọ awọn ọba ilẹ Yoruba.

O ni gbogbo isesi ọba Mufutau lo safihan rẹ gẹgẹ bi awokọse daada ati ẹgbọn fun oun laarin awọn ọba ilẹ Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Oluwo/facebook

Àkọlé àwòrán,

Ọba tó ṣe fi yangàn láàrín ọba Nàìjíríà ni Ọlọ́fà ìlú Offa-Oluwo

Arun Coronavirus sebi ẹni ké ayẹyẹ ọdun kẹwa Ọlọfa kuru sugbọn

Ni ọjọ Kẹjọ osu kaarun ọdun 2010 ni Oba Mufutau gun ori itẹ awọn baba rẹ gẹgẹ bi ọlọfa ikẹrinlelogun ilu Offa.

Lọpọ ibi ti iru nkan ayọ bayi ba ti waye ni awọn ara ilu ti ma n peju si aafin ọba lati ba ọba yọ ku orire.

Oríṣun àwòrán, Oluwo/facebook

Àkọlé àwòrán,

Ọba Gbadamọsi: Olúwòó, ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria fi ìkíni ránṣẹ́ si Ọlọ́fà fún ayẹyẹ ọdún mẹwàá lórí oyè

Sugbọn pẹlu bi arun Coronavirus ti se gbode kan bayi,apejọ ko ni le waye bi yoo ti se wu Ọlọfa tabi awọn ara ilu naa.

Amọ sa loju opo ayelujara ati lori ẹrọ redio nise ni awọn ọmọ ilu naa n gbe orisirisi ikini ati eto kalẹ lati fi ba ọba yọ.

Ni ọjọ Kẹjọ osu kaarun ọdun 2010 ni wọn jawe oye fun ọba Mufutau ti Gomina igba naa nipinlẹ Kwara Bukola Saraki si gbe ọpa asẹ fun un ni ọjọ Kẹsan osu kaarun ọdun 2010.

Òṣìṣẹ́ ààfin mi tí kò bá lo ìbòmú yóò pàdánù isẹ́ rẹ̀-Oluwo

Oluwo pàṣẹ fáwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ láti lo ìbòmú tàbí kí wọ́n pàdánù iṣẹ́ wọn

Oríṣun àwòrán, Emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi Telu 1

Oluwo ti ilu iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti leri leka pe lile loun yoo le oṣiṣẹ aafin rẹ ti ko ba lo ibomu gẹgẹ bi ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ṣe paa laṣẹ.

Ninu Atẹjade, Oluwo ṣalaye pe lilo ibomu yoo pinwọ itankalẹ arun Coronavirus ni ipinlẹ Ọṣun ati jakejado orilẹede NAijiria.

Oluwo ni, "Arun Coronavirus kii ṣe arun ti eeyan n fi ṣere rara. Tootọ ni, o si n pani bi ọgan ni."

Aworan atọnisọna

Iye awọn to ti ni arun naa lagbaye

Group 4

Jọwọ ṣe atunṣe ilana ikansi ayelujara rẹ lati ri ẹkunrẹrẹ rẹ

Orisun: Johns Hopkins University atawọn ajọ eto ilera ilu

Igba ti wọn kede iṣiro awọn to nii kẹyin 5 Oṣù Agẹmọ 2022 10:59 WAT+3