George Floyd Funeral: Ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́fà tó mi àgbáyé nípasẹ̀ ikú George Floyd l'Ámẹ́ríkà

Wọn n gbe oku Floyd lọ si itẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iku ọkunrin adulawọ kan ti a mọ si George Floyd kii ṣe iroyin tuntun mọ, koda wọn ti ṣe isinku rẹ pẹlu.

Amọṣa oniruuru ayipada ati iṣẹlẹ ni iku arakunrin yii ti mu waye kaakiri agbaye.

Iwọde tako iwa ẹlẹyamẹya gbinaya lagbaye lẹyin iku arakunrin adulawọ kan, George Floyd latọwọ awọn ọlọpaa Minneapolis lorilẹede Amẹrika .

Kaakiri agbaye, paapaajulọ lawọn orilẹede Mexico, Canada, Brazil, Australia, New Zealand titi kan awọn orilẹede kan nilẹ Afirika.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eto atunto ati atungbeyẹwo ofin ati ilana iṣẹ ọlọpaa n waye kaakiri orilẹede Amẹrika.

Ọga ọlọpaa ni Dallas, Renee Hall ni awọn alaṣẹ ipinlẹ Dallas ti tẹwọ gba ofin to kan an ni dandan fawọn ọlọpaa lati maa da awọn akẹgbẹ wọn to ba n huwa aitọ lọwọ kọ. Ofin tuntun yii yoo lee dena atunṣẹ irufẹ iṣẹlẹ to mu ẹmi George Floyd lọ lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Minneapolis nigba ti ọlọpaa kan ti orukọ rẹ n jẹ Derek Chauvin gbe orokun lee lọrun mọlẹ.

Lara awọn ayipada ati iṣẹlẹ ti o ti mu waye ree:

  • Iwọde tako ẹlẹyamẹya, iwa ipa awọn ọlọpaa ati ijẹgaba leni lori.
  • Fun igba akọkọ ni ọpọlọpọ ọdun, gbogbo agbaye fi ohun ṣọkan lori iwa ibajẹ awujọ eleyi to mu Iwọde waye kaakiri gbogbo agbaye lati minneapolis ti iṣẹlẹ iku Floyd ti waye titi lọ kan Mexico, Canada, Brazil, Australia, New Zealand titi kan awọn orilẹ€de kan lorilẹede Afirika.
  • Awọn alaṣẹ ilu Minneapolis gbẹsẹ le fifi ẹsẹ fun afunrasi lọrun mọlẹ tofimọ awọn ọna miran tawọn ọlọpaa n lo lati fi mu awọn afunrasi mọlẹ.
  • Gbogbo awọn ọlọpaa to ms si iku arakunrin naa ni wọn ti n fi jofin bayii lẹyin ti awọn alalṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa nibẹ fi kọkọ tẹti lori fifi wọn jofin. Nibayii wọn ti n foju ba ile ẹjọ.
  • Eto atunto ati atungbeyẹwo ofin ati ilana iṣẹ ọlọpaa n waye kaakiri orilẹede Amẹrika.
  • Olori ilu Lousville ti paṣẹ agbeyẹwo ileeṣẹ ọlọpaa nibẹ.
  • Ipinlẹ Dallas ti tẹwọ gba ofin to kan an ni dandan fawọn ọlọpaa lati maa da awọn akẹgbẹ wọn to ba n huwa aitọ lọwọ kọ.
  • Amofin agba Ipinlẹ New Jersey ti ṣalaye pe agbeyẹwo yoo wa fun ilana kan-an -nipa awọn ọlọpaa, eyi yoo si jẹ igba akọkọ laarin ogun ọdun.
  • Awọn ere ti wọn gbe kalẹ ni iranti awsn eeyan to niiṣe pẹlu owo ẹru atawọn iwa ipa ati ẹlẹyamẹya gbogbo ni wọn di wiwo kalẹ.

Awọn alaṣẹ ilu Minneapolis gbẹsẹ le fifi ẹsẹ fun afunrasi lọrun mọlẹ tofimọ awọn ọna miran tawọn ọlọpaa n lo lati fi mu awọn afunrasi mọlẹ. Gbogbo awọn ọlọpaa to ms si iku arakunrin naa ni wọn ti n fi jofin bayii lẹyin ti awọn alalṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa nibẹ fi kọkọ tẹti lori fifi wọn jofin. Nibayii wọn ti n foju ba ile ẹjọ.

Awọn ere ti wọn gbe kalẹ ni iranti awsn eeyan to niiṣe pẹlu owo ẹru atawọn iwa ipa ati ẹlẹyamẹya gbogbo ni wọn di wiwo kalẹ.

Awọn ere adayaba naa fara gba ninu ibinu awọn araalu lasiko iwọde gbogbo.

Ilẹ Gẹẹsi

Wọn gbe ere Edward Colston to wa ni ilu Briston kuro.

Awọn oluwọde ni ilẹ Gẹẹsi wo ere oniṣowo ẹru kan lasiko iwọde wọn. Awọn oluwọde ni Briston ni tiwọn so okun mọ ere Edward Colston naa, wọn si tii ṣubu ki wọn to tii sinu agbami Avon.

Belgium

Wọn gbe ere King Leopold II kuro

Awọn alaṣẹ Antwerp gbe ere Ọba orilẹede Belgium tẹlẹ lasiko ijọba amunisin, Leopold II kuro lẹyin ti awọn oluwọde dana sun un lati fi ẹhonu han lori iṣejọba amunisin.

George Floyd Funeral: Bí ètò ìsìnkú George Floyd ṣe lọ rèé ní ìlú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ kẹsan an oṣu kẹfa ọdun 2020 ni George Floyd wọ kaa ilẹ sun ni ilu ibi rẹ, Houston.

Bi eto isinkun naa ṣe lọ ree.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Floyd dagbere faye lẹyin ti Derek Chavin to jẹ agbofinro nigba naa tẹẹ lọrun mọlẹ titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ awọn abanikẹdunn lo peju sibẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ẹbi ati ọrẹ rẹ naa ko gbẹyin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ijọsin Fountain of Praise ni eto isinkun naa ti waye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibanujẹ nla ni iku Floyd jẹ fun awọn mọlẹbi rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

George Floyd wọ káà ilẹ̀ lọ nílùú Houston l'Amẹrika

Eto isinku George Floyd ti wọ kaa ilẹ lọ niluu Houston lorilẹede Amẹrika nibi ti wọn ti bi i.

George ni ọmọ ilẹ Adulawọ ti ọlọpaa alawọfunfun, Derek Chauvin fi orukun tẹ lọrun pa loṣu to lọ.

Iku rẹ ti ṣe okunfa ifẹhonuhan kaakiri agbaye papaajulọ lorilẹede Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi.

Nancy Pelosi àtàwọn aṣòfin ẹ́gbẹ́ òṣèlú Democrats wọ aṣọ ilẹ̀ Ghana, Kente láti ṣe ìkẹ́dùn George Floyd

Abẹnugan Ile Aṣofin Kekere lorilẹ-ede Amerika, Nancy Pelosi ati awọn aṣofin lẹgbẹ oṣelu Democrats ni wọn wọ aṣọ ilẹ Ghana, Kenke lati ṣe ikẹdun George Floyd ti awọn ọlọpaa pa ni Minneapolis.

O ku diẹ ko pe iṣẹju mẹsan an ni awọn aṣofin yii fi kunlẹ ni iranti iṣẹju mẹjọ ti ọlọpaa naa fi gbe orunkun le Floyd lọrun ti o si n pariwo pe oun ko le e mi.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Lẹyin naa ni awọn aṣofin naa ba awọn akọroyin sọrọ wi pe awọn n se abadofin lọwọ ti yoo mu atunto ba ileeṣẹ ọlọpaa ni orilẹede naa.

Bakan naa ni awọn eniyan lori ẹrọ ayelujara ti bẹrẹ si ni fesi si aṣọ ilẹ Ghana ti awọn aṣofin naa wọ lọ si ile aṣofin naa.

Ni gbogbo agbaye ni ifẹhọnu han iku George Floyd ti waye, ti awọn eniyan si n pe fun atunto lori ajọ ọlọpaa lorilẹede Amerika.

Òní ni ètò ìsìnkú George Floyd yóò wáyé

Oríṣun àwòrán, EPA

Awọn eeyan ilu Houston, ni Texas ni adanu nla ni iku Floyd jẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Ile ijọsin Fountain of Praise yii ni wọn gbe oku Floyd si nibi ti awọn abanikẹdun jorajọ si.

Ọ̀pọ̀ abánikẹ́dùn ti ṣetán láti yọjú síbi ayẹyẹ ìkẹyìn George Floyd lónìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Isin idagbere waye fun George Floyd ni Minneapolis

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ awọn abanilkẹdun lo n ṣọfọ George Floyd ni Houstin to n gbe tẹlẹ ko to lọ si Minneapolis ti wọn ti pa.

Nǹkan mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nipa George Floyd tí ọlọ́pàá fún lọ́rùn pa rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ kẹsan oṣu kẹfa ọdun 2020 ni George Floyd ti ọlọpaa ilẹ Amẹrika kan, Derek Chauvin fi ẹsẹ fun lọrun pa yoo wọ kaa ilẹ lọ.

Ilu Houston to ti dagba ni wọn yoo sin oku George Floyd si.

Ẹgbẹẹgbẹrun un eeyan dudu ati alawọ funfun lo ti n ṣe iwọde papaa julọ l'Amẹrika ati ilẹ Gẹeṣi lori iku George Floyd

Wọnyi ni awọn nnkan mẹwaa to yẹ ki o mọ nipa oloogbe George Floyd:

Houston ni George ti dagba ko to lọ si Minneapolis

Oríṣun àwòrán, @LITE_III

Ni agbegbe Third Ward ni Houston ni George Floyd dagba si.

Koda ilumọọka ni nigba to fi wa nile iwe girama nitori Eleduwa fun ni ẹbun bọọlu gbigba.

Ni nnkan bi ọdun diẹ sẹyin ni George ṣipo pada lọ si Minneapolis lati lọ ṣiṣẹ, nibẹ naa lo ti ṣe kongẹ iku lọwọ awọn ọlọpaa to fun un lọrun.

Floyd Mayweather Jnr ṣeleri gbowo kalẹ fun eto isinku George Floyd

Oríṣun àwòrán, @ComplexSports

Abẹṣẹ ku bi ojo, Floyd Mayweather Jnr. ti ṣe ileri lati gbe gbogbo inanwo eto isinku George Floyd eyi ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹsan an oṣu kẹfa.

Agbẹjọro ẹbi oloogbe George, Ọgbẹni Ben Crump ṣalaye pe ilu rẹ ni Houston ni wọn yoo sin George sii

Leonard Ellerbe to jẹ adari ileeṣẹ Mayweather Promotions lo fidi ọrọ naa mulẹ fawọn akọroyin.

Kanye West ṣèrànwọ́ $2m fún ẹbí George Floyd, yóò tún rán ọmọ rẹ̀ nílé ìwé

Gbajugbaja olorin taka sufe ilẹ Amẹrika, Kanye West ti ṣeranwọ miliọnu meji dọla fun idile George Floyd to ku lẹyin ti ọlọpaa tẹ lọrun mọle ni Minesota.

Kanye West ṣèrànwọ́ $2m fún ẹbí George Floyd, yóò tún rán ọmọ rẹ̀ nílé ìwé

Oríṣun àwòrán, others

Olorin naa ti ko sọ ohunkohun lori ayelujara lẹyin iwọde to tẹle iku ologbe ọhun tun ṣagbekalẹ owo ile iwe fun Gianna Floyd, to jẹ ọmọ ọdun mẹfa ti Floyd fi saye lọ.

Aṣoju Kanye West to ba ileeṣẹ iroyin CNN sọrọ ni owo naa wa idile Floyd, Ahmaud Arbery ati Breonna Taylor.

George Floyd: Àwọn olùfẹ̀hónúhàn wó ère ówò ẹrú lulẹ̀ ní UK

Ifẹhonuhan lati tako iwa ẹlẹyamẹya l'Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi bẹyẹn yọ, lẹyin tawọn olufẹhohan wo ere oniṣowo ẹru, Edward Colston ni Bristol.

Akọsilẹ fidi rẹ mulẹ pe Ọgbẹni Colston ko awọn eeyan alawọdudu bii ẹgbẹrun un lọna ọgọrin lati ilẹ Afirika lẹru lọ si Amẹrika nigba owo ẹru.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa Avon & Somerset ti fi atẹjade sita pe awọn agbofinro yoo ṣewadi awọn ti wọn ere naa.

Ogunlọgọ eeyan l'Amẹrika ati nilẹ Gẹẹsi ni wọn ti n ṣe ifẹhonuhan lati ọsẹ to lọ lori ọmọ ilẹ Afirika Ọgbẹni George Floyd to ku lẹyin ti ọlọpaa alawọfunfun kan, Derek Chauvin fi orunkun fun un lọrun.

Ọpọ alawọfunfun gan an lo gbaruku ti awọn alawọdudu ninu iwọde ti wọn n ṣe lati tako iwa idẹyẹsi ati ẹlẹyamẹya.

George Floyd ní àrùn coronavirus

Arakunrin adulawọ, George Floyd ti iku rẹ ti n da rogbodiyan silẹ kaakiri orilẹede Amẹrika atawọn ilu nlanla miran jakejado agbaye ni wọn ni ayẹwo fihan pe o laarun coronavirus ko to jade laye.

Ninu iwe esi ayẹwo iku rẹ ti ileṣẹ ilera Hennepin County Medical center office gbe jade ni wsn ti ṣalaye pe ayẹwo iku rẹ fihan pe o laarun coronavirus ni ọjọ kẹta oṣu kẹrin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Abajade naa ṣalaye pe pẹlu bi iṣẹda kokoro arun naa ṣe ri, o lee gbe ni ags ara fun ọpọlọpọ ọsẹ. Wọn ni o ṣeeṣe ki arakunrin naa o ma ri apẹrẹ arun naa lara rẹ titi di igba to fi ẹmi silẹ; amọṣa o fara han ninu ayẹwo naa.

George Floyd lọ kawe ni Texas

George gbabọọlu alapẹrẹ fun ileewe South Florida State to wa Avon Park, ni Florida nibi to ti kẹkọọ laarin ọdun 1993 si 1995.

Lẹyin naa lo tun gberasọ lọ si Texas lati tẹsiwaju ẹkọ rẹ ni fasiti A&M to wa ni Kingsville, amọ ko gboye jade ni fasiti ọhun.

Ọlọpaa ti mu George Floyd lọpọ igba

Lọpọ igba lawọn ọlọpaa ti mu George Floyd fun ẹsun kan tabi omiiran lorilẹede Amẹrika.

Lọpọ igba ni wọn ka oogun oloro mọ ọ lọwọ eyi to jẹ ki wọn fi ọwọ sinkun ofin mu un.

Wọn fi ẹsun idigunjale kan George Floyd lọdun 2007

Ni ọdun 2007, wọn ẹsun idigunjale kan George Floyd.

Koda ẹwọn ọdun marun un gbako ni wọn kan an lọdun naa.

Ṣugbọn iroyin sọ pe George bẹrẹ si ni jara mọ iṣẹ lẹyin to jade lẹwọn tan.

George Floyd bi ọmọbinin lọdun 2014

George Floyd bi ọmọbinrin Gianna Floyd pẹlu ọrẹbinrin rẹ, Roxie Washington lọdun 2014.

Koda ọrẹbinrin rẹ ọhun sọ pe ọmọbinrin ti George bi fihan pe eeyan ti ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyin lawujọ ni.

George padanu iṣẹ iṣẹ rẹ tori ajakalẹ aarun coronavirus l'Amẹrika

Iṣẹ eṣọ ni George Floyd n ṣe pẹlu ileeṣẹ kan, Salvation Army charity ni Minneapolis.

Bakan naa lo tun n wa ọkọ nla akẹru, o tun n ṣe eṣọ nile ijo kan ti wọn n pe ni Conga Latin Bistro.

Ṣugbọn George wa lara ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ ilẹ Amẹrika to padanu iṣẹ wọn nitori ajakalẹ aarun covid-19.

Ọjọ kẹedọgbọn oṣu karun un ni wọn pe ọlọpaa si i pe o fẹ fi owo ayederu ra siga.

Oríṣun àwòrán, AFP

Dokita Micheal Baden to jẹ oṣiṣẹ fẹyin ileeṣẹ ayẹwo oku ni ilu New York, to tun jẹ ọkan lara awọn meji to yẹ oloogbe Floyd wo ṣalaye pe ko ba ti kede pe o laarun naa ti ko ba ṣe pe o di pataki lati lee jẹ ki gbogbo awọn to ti ni ohun kan tabi omiran lati se pẹlu rẹ nigba aye rẹ o mọ igbesẹ to tọ latigbe bayii.

Floyd: Adarí ètò àbò ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti fẹ̀sùn kan ààrẹ Trump lórí ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ eniyan lo ti bu ẹnu atẹ lu bi Aarẹ ilẹ Amerika, Donald Trump ṣe n wuwa lori iṣekupani George Floyd

Adari eto aabo lorilẹede Amerika tẹlẹri, James Mattis ti fẹsun Aarẹ orilẹede Amerika, Donald Trump pe oun gan an lo n da wahala ẹlẹyamẹya silẹ ni ilẹ Amerika.

Mattis ni ibanujẹ ọkan ls jẹ fun oun pẹlu bi aarẹ Trump ṣe gbe ọrọ ifẹhọnu han lori iṣẹkupani ọmọ ilẹ Adulawo, George Floyd ti awọn ọlọpaa alawọ fufu pa ni Minnesota, ni Amerika.

O ni Trump n ṣi ipo rẹ lo, ti o si n ṣe atilẹyin fun awọn to n ṣe iwode tako iṣẹkupani Floyd bii aarẹ tẹlẹri, Barack Obama ṣe ṣe nigba ti o wa ni ipo.

Amọ aarẹ Trump bu ẹnu atẹ lu Mattis ati ipo rẹ gẹgẹ bi ọgaagun.

Ọdun 2018 ni Mattis kọ iwe fi ipo silẹ lẹyin ti Aarẹ Trump fi ipinnu rẹ han lati ko awọn ọmọogun ilẹ Amerika kuro ni Syria.

Èmi ni Ààrẹ tó ṣe rere fún ilẹ̀ adúláwọ̀ jù - Donald Trump

Aarẹ Donald Trump ti tun sọ wi pe oun ni aarẹ to ti ṣe rere fun awọn eeyan dudu ju ninu gbogbo aarẹ to ti jẹ, o ni ayafi aarẹ Abraham Lincoln nikan loun yọ silẹ.

Eyi jẹ ohun ti aarẹ Trump ta pada si Joe Biden, igbakeji aarẹ ana ni Amẹrika to sọ wi pe oun ti ṣe daadaa fun awọn alawọdudu ju ohun ti alatako rẹ ti ṣe lọ laarin ọdun mẹtalelogoji.

Oríṣun àwòrán, @realDonaldTrump

Àkọlé àwòrán,

Èmi ni Ààrẹ tó ṣe rere fún ilẹ̀ adúláwọ̀ jù - Donald Trump

Ọgbẹni Joe Biden bu ẹnu atẹ lu Trump pe o n fi ọrọ to wa nilẹ yii fa oju awọn alatilẹyn rẹ mọra ni pe "o n tẹ ifẹ orirun rẹ lọrun ni".

Bakan naa si ni aarẹ Trump bu ẹnu atẹ lu awọn apaniyan, awọn adunkokomọni, awọn janduku ati adigunjale ti o nigbagbọ pe awọn lo wa lẹyin gbogbo ifẹhonu han to n waye lọwọ lọwọ nilẹ Amẹrika.

Ṣé ó tọ́ kì Ààrẹ Trump máa fi Bíbélì jẹ́rìí?

Floyd US Protest: Ó ṣe wá ní kàyéfì pé Ààrẹ Trump lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì - Ìjọ Kátólìkì

Oríṣun àwòrán, Trump

Àkọlé àwòrán,

Ṣé ó tọ́ kì Ààrẹ Trump máa fi Bíbélì jẹ́rìí?

Isọri awọn adari ẹsin kan kaakiri Amẹrika ti lodi si igbesẹ Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti o ti gbe bibeli soke niwaju ile ijọsin St. John ni Washinton DC .

Wọn ni eyi ṣẹlẹ lẹyin ti awọn janduku jo ile ijọsin naa nina lalẹ ọjọ ti wọn n fẹhonu han.

Aarẹ Donald Trump fi fọnran ara rẹ soju opo Twitter rẹ ninu eyi to ti gbe bibeli soke to si n sọrọ wi pe titobi ni Ọlọrun.

Iṣẹlẹ yii waye ni St John's Episcopal Church ni isọda ọna to wa lọgangan iwaju ile Aarẹ.

Eyi ni wọn ni ko wulẹ wu ọpọ ninu awọn ojiṣẹ Ọlọrun lori rara gẹgẹ bi orilẹ-ede America ṣe n gbiyanju lati koju ipenija onibeji to n ba wọn finra iyẹn ti ajakalẹ aarun Coronavirus lẹgbẹ kan ati ifẹhonuhan to n waye tori oṣelu orilẹ-ede naa.

Kini awọn Oluṣọ agutan n sọ?

Biṣọọbu ijọ Aguda ni Washington, Alufa agba Mariann Budde ni "Aarẹ kan deede lo bibeli eyi tii ṣe ọrọ ijinlẹ julọ ninu aṣa awọn ẹlẹsin Kristẹni lai gba aṣẹ to si fi n ṣe ipilẹ ọrọ to lodi si ẹkọ Jesu Kristi.

Bakan naa ni alufa mii to tun jẹ agbẹnusọ fun ijọ Aguda nibẹ, James Martin fi si oju opo Twitter rẹ pe:

"Ẹ jẹ ki n fi yee yin pe iwa iṣodi ni eyi. Bibeli kii ṣe ohun elo ori itage. Ijọ kii ṣe ibudo fọto. Ẹsin kii ṣe ohun elo oṣelu. Ọlọrun kii ṣe nkan iṣere."

Kini o wa ń ṣẹlẹ bayii?

Olukọ bibeli kan, Rabbi Jack Moline ni bi pun ṣe ri iṣesi aarẹ Trump yii lẹyin to ṣẹṣẹ fi ọwọ ofin ijọba ologun tu awọn afẹhonu han ka tan jẹ lilo ẹsin Kristẹni lọna aitọ gbaa.

Wọn fi ye ni pe aarẹ Trump ko darapọ mọ ijọ kankan ni pato, ẹẹkọọkan lo maa n lọ jọsin to si ti sọ ọ ni ọpọ igba pe oun ko fẹran lai maa tọrọ idarijin ẹṣẹ lọwọ Ọlọrun.

Ẹwẹ, bi ko ba tilẹ ro o pe ile ijọsin wulo fun aye rẹ, o ni i ṣe pẹlu ọjọ iwaju oṣelu rẹ.

Bi ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba:

Lọdun 2016, ida mọkanlelọgọrin awọn ijọ onihinrere lo dibo fun Trump ti ida ọgọta awọn ọmọ ijọ Katoliki si yan an dipoo alatako rẹ,

Hillary Clinton ti ida mẹtadinlogoji ijọ Katoliki pere dibo fun. Eyi ti mu ko jẹjẹ atilẹyin fun awọn ẹlẹsin to fibo wọn gbe e wọle.

Se ẹ wa rii pe eyi lo ṣalaye idi ti ẹni ti wọn ni kii lọ ṣọọsi deede sibẹ to tun wa n ja fun ki wọn ṣi awọn ile ijọsin silẹ titi ọjọ kejilelogun, oṣu karun un bibẹẹ kọ oun yoo gbe igbesẹ lai fi tawọn gomina ṣe.

O le ni ida marunlelọgọrin awọn ijọ onihinrere to kan sara si bi aarẹ Trump ṣe n koju aarun Coronavirus yii.

Sugbọn bi awọn kan ṣe ti wa lẹyin Trump, gbogbo orilẹ-ede ọhun ti pinya bayii ti awọn kan n sọ pe awọn lodi si bi aarẹ Trump ṣe n ṣe tirẹ

Àkọlé fídíò,

George Floyd: Àwọn ọlọ́pàá darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọ́de lórílẹ̀èdè Amẹ́ríkà

Nítorí George Floyd, Àwọn ọlọ́pàá darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọ́de lórílẹ̀èdè Amẹ́ríkà

George Floyd protests: Àwọn ọlọ́pàá darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọ́de lórílẹ̀èdè Amẹ́ríkà láti wọ́de lórí adúláwọ̀ t'ọ́lọ́pàá ṣekúpa

Ayẹwo aladani ti wọn ṣe fun oku ọmọkunrin alawọdudu tawọn ọlọpaa ṣekupa lorilẹede Amẹrika, George Floyd ti fihan pe ọkunrin naa ku lẹyin ti ko ri afẹfẹ mi sinu mọ.

Awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti ẹbi oloogbe George bẹ lọwẹ lati ṣe ayẹwo lori oku ọkunrin sọ pe ok u lẹyin ti ọlọpaa Minneapolis fun un lọrun.

Esi ayẹwo naa yatọ si eleyi tawọn ti ijọba bẹ lọwẹ lati ṣee nitori esi naa ko fidi rẹ mulẹ pe wọn fun un lọrun pa ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Esi ayẹwo ti ijọba ṣe tun sọ pe Ọgbẹni Floyd ku nitori awọn ailera kan to wa lara rẹ tẹlẹ ni.

Ṣugbọn awọn dokita meji tawọn ẹni ẹbi rẹ gba lati ṣe ayẹwo ohun to ṣokunfa iku rẹ, esi ayẹwo naa si fihan pe wọn fun un lọrun pa ni.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá ṣòfò lásìkò ìfẹ̀họ́nú hàn nítorí ìṣèkúpani George Floyd

Awọn ọlọpaa ati awọn afẹhọnu han ti gbena woju ara wọn lorilẹede Amerika lori iṣekupani Geaorge Floyd gba ọwọ ọlọpaa Minnesota.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Gomina ipinlẹ Minnesota ni ifẹhọnu han naa ti koja bo ṣe yẹ nitori ọpọlọpọ dukia si ti sọfọ si ifẹhọnu han naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Lati ipinlẹ New York de awọn ipinlẹ miran ni awọn eniyan ti fa rogbodiyan lasiko ifẹhọnu han naa, ti wọn si jo aago ọlọpaa pẹlu.

Ni Ọjọ Eti, ni ile Aarẹ ni Amerika, White House wa ni tit pa lẹyin ti awọn eniyan fariga ni iwaju ile aarẹ ohun.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọlọpaa tẹlẹri naa, Derek Chauvin to jẹ alawọ fun fun lo fi erunkun fun ọrun George Floyd to jẹ ọkunrin adunlawọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Iṣekupani yii ti jẹ bi irunu fun awọn ọmọ ilẹ Afrika to wa ni orilẹede Amerika ti wn ti lugbadi ki awọn ọlọpaa alawọ fun fun ṣe wọn basubasu.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìwọ́de bẹ̀rẹ̀ ní Minnesota lórí àwọn ọlọ́pàá mẹrin to pa ọmọ adulawọ ni Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwọde loriṣiriṣi ti n waye ni Minneapolis lorilẹede Amẹrika lori iku adulawọ kan, George Floyd.

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọrọ di iṣu ata yan an yan an ni alẹ Ọjọru pẹlu ibọn yinyin ati ile fifọ

Eyi ni aṣalẹ keji ti awọn eeyan to n fi ẹhonu han lori bi awọn ọlọpaa kan ṣe ṣekupa George Floyd.

Oríṣun àwòrán, Darnella Frazier

Àkọlé àwòrán,

Iṣẹ ti bọ lọwọ ọlọpaa Minnesota mẹrin to pa ọmọ alawọdudu ni Canada

George Floyd: Ọlọpaa mẹrin gba iwe idaduro lẹyin iku ọmọ alawọdudu ni Minnesota

Adari ọlọpaa Minneapolis Madaria Arradondo sọ pé awọn ọlọpaa mẹrin to lọwọ ninu ǹkan to ṣeku pa ọmọ alawọ dudu George Floyd ti di oṣiṣẹ igba kan ri

Fọran ṣafihan ọkunrin kan George Floyd to n pariwo pe oun ko le mi fun ọlọpaa alawọ funfun to de mọlẹ lasiko ti wọn n gbiyan ju lati mu

Isẹlẹ yii tun muni ranti ọkunrin alawọ dudu miran Eric Garner to ku lẹyin ti ọlọpaa mu ni New York City lọdun 2014.

Ajọ FBI ti ni awọn yoo ṣe iwadii iṣẹlẹ to waye lalẹ ọjọ aje.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọlọpaa Minnisota sọ pe ọgbẹni Floyd ẹni ọdun mẹrindinlaadọta jẹ aṣọna ni ile ounjẹ kan, o sì ku lẹyin ti ọlọpaa ṣee bi ko se yẹ.

Lọjọ iṣẹgun ni Jacob Frey fidi rẹ mulẹ pe iṣẹ ti bọ lọwọ awọn ọlọpaa mẹrin ti aje ọrọ naa si mọ lori.

Saaju ni Frey ti sọrọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ to sì salaye pe iṣẹlẹ naa bani lọkan jẹ gidi.

Eyi n tọka si iwa ika ti ọpọ awọn ọlọpaa ilẹ Amerika n hu si awọn alawọ dudu ilẹ Amerika, lara rẹ ni eyi to waye laipẹ yii ni bi ti ọlọpaa Maryland kan ti yin ọkunrin kan nibọn ninu ọkọ ọlọpaa.

Iṣẹlẹ Minneapolis bẹrẹ pẹlu ẹsun pe oluraja kan n gbiyanju lati na ogun dọla ayederu ni ilé itaja kan.

Awọn ọlọpaa ri afunra si naa ni inu ọkọ rẹ gẹgẹ bi atẹjade ọlọpaa ṣe sọ. Wọn ni ọkunrin naa ko salaye ara rẹ lori moto to joko si sugbọn o joọ bi ẹni pe o ti mọti yo

Oríṣun àwòrán, Twitter/ruth richardson

Lẹyin ti ọlọpaa sọ fun ki o kuro lara ọkọ rẹ ko da awọm ọlọpaa lohun gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ.

Awọn ọlọpaa pada ri mu nínú fọran to le ni iṣeju mẹwaa, wọn fi ẹwọ de lọwọ wọn si fun mọlẹ , sugbọn o jọ bi ẹni pé o nilo iranwọ awọn eleto ilera.

Ọpọ awọn tọrọ naa soju wọn ni wọn n ke si ọlọpaa pe ko gbe orokun rẹ kuro lọrun ọkunrin ọun ati pé ko mira mọ. Okan ni " imu rẹ ti n ṣẹjẹ" nigba ti omiran n kigbe pé" dide kuro lọrun rẹ"

Loju ẹsẹ o jọ bi ẹni pe ọkunrin naa ko mira mọ ki wọn to gbe sinu ọkọ ambulansi.

Ọpọ lo ti n wode lálẹ ọjọ iṣẹgun niwaju ile iṣẹ ọlọpaa Minneapolis ti awon ọlọpaa si n fi tajutaju tu wọn ka

#icantbreathe lọrọ to gba oju opo twitter kan lowuro oni ni Naijiria

Bakan naa ni awon miran loju opo twitter ni yiyọ awon ọlọpaa naa nisẹ ko to nitori to ba ṣe pe alawọ dudu lo pa alawọ funfun ní, ẹjọ ipaniyan ni wọn yoo da ti o si le lọ ẹwọn gbere