Rape cases in Nigeria: Ẹ sọ ìlò afẹ́fẹ́ aláta àti ìbọn ònírọ́bà di òfin fáwọn obìnrin - Oluwo

Oluwo

Oríṣun àwòrán, Instagram/emperortelu1

Oluwo tilu Iwo, ọba Abddulrasheed Adewale Akanbi Telu Kinni, ti rọ ijọba apapọ lati sọ ilo afẹfẹ alata ati ìbọn onirọba di ofin fawọn obìnrin, eyi ti yoo jẹ ara ohun elo idaabo bo lọwọ awọn afipabanilọpọ.

Ọba Akanbi gbe imọran yii kalẹ ninu atẹjade kan to fisita fawọn akọroyin, eyi to fi n koro oju si iṣẹlẹ ifibanilọpọ to n waye lojoojumọ yika Naijiria.

Oluwo woye pe ijọba apapọ yoo lee raga bo ẹmi ọpọ obinrin lọwọ ewu ifipabanilọpọ, to ba fi aaye gba wọn lati maa lo awọn ohun elo yii fi daabo bo ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Instagram/emperortelu1

"Awọn obinrin yoo yoo ni anfaani ati ko eroja naa sinu apamọwọ wọn, nitori iṣẹlẹ fifi ipa ba ni lopọ yii ti n pọ ju bo ṣe yẹ lọ."

Bakan naa ni ọba alaye ọhun daba pe ki ijọba mu adinku ba iṣẹlẹ naa nipa agbekalẹ ofin ti yoo mu ki awujọ wa bọ lọwọ iwa ika yii, ti ọwọ yoo si wa fun awọn obinrin.

Àkọlé fídíò,

Mo fẹ́ máa polongo oúnjẹ ilẹ̀ wa ló jẹ́ kí n máa fi oúnjẹ bíi àmàlà ya àwòrán