Abacha: Al Mustapha ní ète ìdìtẹ̀ gbàjọba méjọ ni Sani Abacha borí

Abacha

Oríṣun àwòrán, others

Loni tii ṣe ayajọ ijọba alagbada ni Naijiria, Al Mustapha to jẹ osisẹ alaabo agba fun aarẹ ologun tẹlẹ, Sani Abacha ti sọrọ nipa aseyọri ọga rẹ lori aleefa.

Al Mustapha lasiko to n kopa lori eto kan ni ikanni BBC Hausa salaye pe olootọ ilu, ni ika ilu ni ọrọ Sani Abacha, kii sì ṣe ẹni abuku rara nitori ọpọ aṣeyọri to ṣe.

Mustapha ni ẹnu n ya oun lori bi ọpọ eeyan ṣe n sọrọ abuku nipa Abacha nitori pe asiko to gori oye, owo ti Naijiria ni nipamọ loke okun ko to biliọnu meji dọla rara.

Ṣugbọn laarin ọdun mẹrin ati oṣu mẹjọ, Abacha ti sọ owo ti Naijiria ko pamọ silẹ okeere di biliọnu mẹsan dọla, amọ gbogbo owo yii lo parẹ lẹyin oṣu mẹsan ti Abacha ku.

Oríṣun àwòrán, @doubleblessin

"Eeyan pataki to gbe Naijiria de ipo giga, to si mu agbega ba eto aabo ati oju ti awujọ agbaye fi n wo Naijiria, lo wa di ẹni ti awọn eeyan kan n fi ẹnu saata rẹ, sugbọn awọn eeyan to pin owo ti Abacha fi silẹ si wa laye lai si ẹni to fi ọwọ kan wọn."

Bakan naa lo salaye pe, kii ṣe Abacha nikan lo da pinnu lati ko owo pamọ sáwọn banki loke okun, nitori níbi ipade awọn eeyan ti ọrọ Naijiria gberu, to fi mọ awọn ọba alaye ni wọn ti ṣe ipinnu naa.

O ni nigba ti wọn fẹ fi ofin de Naijiria ni awọn pinnu lati ko owo pamọ silẹ okeere, ki iya maa ba jẹ orilẹ-ede Naijiria nigba ti ofin idẹyẹsi naa ba de.

Oríṣun àwòrán, others

"A pe awọn Emir ati ijoye jọ lati ẹkún guusu ati ariwa Naijiria pẹlu awọn eekan ilu, awọn eeyan to wa ninu ijọba ati awọn ti ko si nibẹ, A ṣe ipade naa ni ibudo igbafẹ awọn ologun Camp Bassey, ta si pinnu lori agbekalẹ ofin idunkooko mọ Naijiria, ta si fi ẹnu ko lori awọn igbesẹ kan.