Ghost workers in Nigeria: Àkàrà tú s'épo fún ẹgbẹ̀rún kan ayédèrú òṣìṣẹ́ SUPEB ní Kwara -EFCC

Magu

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Ajọ to n gbogun ti iwa jegudujera lorileede Naijiria EFCC sọ pe asiri awọn ayederu oṣiṣẹ ẹgbẹrun kan ajọ to n ṣakoso eto ẹkọ alakọbẹrẹ nipinlẹ Kwara ti tu si awọn lọwọ.

Orukọ awọn ayederu oṣiṣẹ yi lawọn kan gb'ọna eburu fi sinu orukọ awọn to n ṣiṣẹ ti wọn si n lu owo oṣu wọn ni ponpo.

Olori ajọ naa to n bójú tó ẹka ipinlẹ Kwara lo fi ọrọ yi to awọn oniroyin leti nilu Ilorin lọjọbọ.

Ọgbẹni Isyaku Sharu sọ pe ninu awọn ti awọn mu lati wa wí tẹnu wọn lori ọrọ yi ni akowe agba kan ati oludari ileesẹ ijọba labẹ ijọba ipinlẹ Kwara kan naa wa.

Loju opo Twitter Efcc bakan naa wọn fi sibe wí pe awọn ti ri ọwọ to to miliọnu mejidinlogoje naira gba pada lọwọ awọn to ku owo ọba ni ponpo.

O tun fikun ọrọ rẹ pe awọn ti ṣaaju da awọn owo kan t'awọn ri gbs pada fun Gomina Kwara, Abdulrahman Abdurazaq

Ajọ Subeb lo yẹ ki o ma mojuto ọrọ eto eko alakọbẹrẹ ni Kwara ṣugbọn ẹnu ko sìn lẹyin ajọ naa pelu bi awọn olukọ ko se ri owo oṣu gba deede ti awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ko si wa nipo to wu ni lori.