Ẹ yé fipá bá obìnrin lòpọ̀ mọ́, ìbálòpọ̀ kìí ṣe dandan - Afẹ̀hónúhàn

Ẹ yé fipá bá obìnrin lòpọ̀ mọ́, ìbálòpọ̀ kìí ṣe dandan - Afẹ̀hónúhàn

Ẹgbẹ to n ja fun idagbasoke ati igbeaye awọn ọdọ, YISED ẹka ipinlẹ Oyo ti ṣe iwọde lati fi aidunu wọn han lori ifipa bani lopọ ati iṣekupani to n peleke si ni Naijiria.

Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ati awọn ọmọ naa atawọn ara ilu lo peju sibi ọhun iwọde ọhun.

Adari ẹgbẹ naa, Olarotimi Smith sọ pe o yẹ ki ijọba ṣe ofin ti yoo fi iya jẹ gbogbo awọn afipa bani lopọ.

Wọn ni iwa ẹranko ni iwa ifipa bani lopọ, ati pe o yẹ ki awọn ọkunrin le jọwọ obinrin to ba ni oun ko fẹ ni ibalopọ lai fi ṣe boya ololufẹ ẹni ni tabi aya ẹni, tabi ẹlomiran.

Lẹyin naa ni wọn rawọ ẹbẹ si awọn lati dẹkun iwa ifipa bani lopọ nitori obinrin naa waye tiwọn ni.

Ẹkunrẹrẹ bi iwọde naa ṣe lọ wa ninu fidio yii.