Working religious women: Mo rí i pé kò sí obìnrin Mùsùlùmí tó n ṣe bàtà ló jẹ́ kí n kọ́ ọ - Aminat Adegoke

Working religious women: Mo rí i pé kò sí obìnrin Mùsùlùmí tó n ṣe bàtà ló jẹ́ kí n kọ́ ọ - Aminat Adegoke

Elehaa Amina Adegoke to n ṣe bata ni BBC lọ ba lalejo lati jẹ ki awọn ọdọ, paapaa awọn obinrin to gba ẹsin ri awokọṣe rere lasiko yii.

Iṣẹ ni iṣẹ n jẹ ni ọrọ awọn agba nilẹ ku ootu, oojiire bi?.

Aminat jẹ iyawo ile ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ti o gba ẹha lọdọ ọkọ rẹ ninu ẹsin Islam lai kabamọ.

O ṣalaye bi oun ṣe lọ kọ iṣẹ bata ṣiṣe ati irufẹ atilẹyin ti ọkọ rẹ fun un lasiko naa.

Eyi tun jẹ iṣẹ to ran si awọn ọkọ obinrin to ba gba ẹsin yala ti Musulumi tabi ti Kristiẹni tabi ti ẹlẹsin abalaye lati maa pese iranlọwọ ati atilẹyin to yẹ fun wọn.

Amina ṣalaye bi awọn onibara rẹ ọkunrin ṣe maa n fi Whatsapp baa sọrọ nitori wọn ti mọ pe Elẹhaa ni oun tabi ki awọn iyawo wọn ba oun sọrọ tabi ki wọn ba ọkọ oun sọrọ lori ẹrọ foonu oun.

O fihan pe ẹsin ko sọ pe ki eeyan ma ni apa lati ṣiṣẹ.

Elẹhaa Amina Adegoke wa gba awọn obinrin to gba ẹsin bii tirẹ niyanju pe ẹha ko yẹ ko di wọn lọwọ lati ṣe aṣeyọri.

O ni ki wọn gbiyanju ipa wọn pẹlu adura lọwọ Olorun fun aṣeyọri.