NUPENG Strike: Ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ epo rọ̀bì NUPENG so ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n gùnlé l'Eko rọ̀

NUPENG

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic

Ẹgbẹ awọn awakọ epo rọbi ni Naijiria, NUPENG ti so iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ to gunle lọjọ Aje ni ipinlẹ Eko rọ.

Eleyi wa ninu atẹjade kan ti NUPENG ati ipinlẹ jọ fi sita lọjọ Aje.

Kọmiṣọnna for ohun amuṣagbara ati ohun alumọnni nipinlẹ Eko, Olalere Odusote ati igbakeji aarẹ NUPENG, Solomon Kilanko lo jọ buwọ luwe naa.

Oludamọran Gomina Babajide Sanwo-Olu lori ọrọ iroyin ori ayelujara, Jubril Gawat lo fọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ.

Atẹjade naa ṣalaye pe ẹgbẹ NUPENG pinnu lati so iyanṣẹlodi naa rọ lẹyin ti ijọba ipinlẹ Eko ṣepade pẹlu wọn.

Ijọba Eko ti sọ pe ohun yoo gbe igbimọ kan dide lati ṣiṣẹ lori ohun ti ẹgbẹ NEPENG fẹ ki ijọba ṣe fun wọn.

A ti gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ ní ìpílẹ̀ Eko- NUPENG

Ẹgbẹ awọn awakọ epo rọbi ni Naijiria, NUPENG ti gunle iyanṣẹlodi ọlọjọm gbọọrọ ni ipinlẹ Eko.

Igbakeji akọwe apapọ fun ẹgbẹ naa, Adamson Momoh sọ fun BBC Yoruba pe, idi iyanṣẹlodi naa ko ṣẹyin bi ijọba Eko ṣe kọti ikun si gbogbo ibeere wọn atẹyinwa.

O ni "Ipinlẹ Eko ni pupọ ninu awọn iṣoro ti a doju kọ ti n waye."

"Lara awọn iṣoro naa ni opopo na ti ko dara, bi awọn agbofinro atawọn ọmọ ita ṣe maa n lo igboju lati gba owo lọwọ awọn eeyan wa, ati bẹẹ bẹẹ lọ."

Momoh ni ijọba ipinlẹ Eko lo yẹ ko wa ojutu si awọn iṣoro ọhun, idi ree ti iyanṣelodi naa ṣe n waye ni ipinlẹ naa.

O ni NUPENG n fẹ ki ijọba Eko wa ọna abayọ si sunkẹrẹ-fakẹrẹ to n waye ni agbegbe Apapa ki ọkọ epo lee ri aye kọja.

Oríṣun àwòrán, @globalextra

Momoh tẹsiwaju pe: "Fun apẹrẹ, epo wa ni ileeṣẹ MRS, ṣugbọn a ko lee ko epo nibẹ nitori awọn 'container' to di ọna mọ ọkọ wa, ṣe kii ṣe ijọba Eko lo yẹ ko wa ojutuu si iru iṣoro bayẹn, abi ileeṣẹ LASTMA kọ lo n risi ọrọ oju popo ni ipinlẹ Eko?"

O fi kun un pe ojuṣẹ ijọba Eko ni lati ṣatunṣe opopona to ti bajẹ nitori ọna ti ko dara lo n fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ.

Bo tilẹ jẹ pe o ni itakurọsọ n lọ lọwọ laarin NUPENG ati ijọba Eko, Momoh sọ pe iyanaṣẹlodi ọhun yoo tẹsiwaju titi di igba ti ijọba Eko yo gbe igbesẹ ọna abayọ si iṣoro ti wọn n doju kọ.

Àkọlé fídíò,

BBC Africa Eye: ìwádìí ìkọ̀ks BBC fihàn pé àwọn kan ń jí ohun èèlò ìdáàbòbò ìjọba tà nígbo

Ẹwẹ, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iyanṣẹlodi ọhun, kọmisọnna eto iroyin ni ipinlẹ Eko, Gbenga Omotosho sọ pe ijọba apapọ lo ni NUPENG, nitori naa ijọba apapọ lo yẹ ko yanju ọrọ ọhun.

Omotosho ni igbimọ amuṣẹya kan ti ijọba apapọ gbe kalẹ lati da si sunkẹrẹ-fakẹrẹ to wa ni Apapa n ṣiṣẹ lọ, ijọba Eko si fọwọsowọpọ pẹlu wọn.

Omotosho pari ọrọ rẹ pe, ijọba Eko yoo maa wo bi ọrọ naa ṣe n lọ lati mọ igbesẹ to kan.

Àkọlé fídíò,

Teach your children Yoruba: Wo àwọn òyìnbó tó ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ní Michigan, America