Water Resources Bill: Wo ohun tó wà nínú òfin nípà àbádòfin lórí omi tí ìjọba rẹ́ buwọ́lù

Water Resources Bill: Wo ohun tó wà nínú òfin nípà àbádòfin lórí omi tí ìjọba rẹ́ buwọ́lù

Oríṣun àwòrán, Others

Ọdun 2018 ni ijọba Naijiria kọkọ mu aba naa wa siwaju ile igbimọ aṣofin kẹjọ.

Nigba ti ile igbimọ aṣojusofin si fọwọ si aba naa, ṣe lo kuna nile aṣofin agba gẹgẹ bi Godswill Akpabio to jẹ adari ẹgbẹ to kere ju nile ko ṣe gba a wọle.

Bakan naa, Bukola Saraki to jẹ aarẹ ile igbimọ aṣofin nigba naa ni ki wọn ni ki wọn kọkọ gbe abadofin ọhun ti na ki ijọba fi ṣe awọn atunṣe kan ki wọn wa gbe e pada wa ṣugbọn eleyi ko ṣẹlẹ titi ti saa wọn fi pari.

Àkọlé fídíò,

Toyin Atoyebi mechanic: Ẹ wo Toyin, ọmọbinrin ọdún 16 tó ń tún skadà àti gẹnẹrátọ̀ ṣe ní

Nigba to tun di inu oṣu keje ọdun 2020, ijọba tun un gbe wa siwaju ile igbimọ aṣofin kẹsan eyi si ti n mu ọpọ ọmọ Naijiria yari fohun silẹ.

Lara awọn to ti kẹnu bọ ọrọ abadofin yii ni Ọjọgbọn Wole Soyinka, gomina Samuel Otorm ti ipinlẹ Benue, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ́, Afenifere ati bẹẹ bẹẹ lọ tori naa, o lee koba irẹpọ orilẹede.

Ẹwẹ, ijọba ti ṣalaye pe abadofin to ti wa niwaju ile igbimọ aṣofin kii ṣe tuntun bi ko ṣe pe ijọba kan fi awọn nkan kọọkan kun aba naa ni ko le wa ni ibamu pẹlu bi wọn ṣe n ṣe lagbaye.

Ki ni abadofin lori omi fun ọdun 2020?

Ofin mẹrin ọtọọtọ ni ijọba ko papọ di odidi kan si abadofin lori omi fun ọdu n 2020. Abala ofin mẹrẹẹrin si jẹ ti ọdun 2004.

Abadofin naa n wa ki abojuto gbogbo orisun omi yala loke eepẹ ni tabi labẹ ilẹ ko wa labẹ akoso ijọba apapọ.

Gẹgẹ bi minisita eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed ṣe sọ, wọn ṣe alakalẹ abadofin ọhun lati pese abojuto nipa ikọṣẹmọṣẹ ti yoo si wulo fun gbogbo ọmọ Naijiria. O fi kun un pe ijọba ko lẹbọ kankan lẹru lori ọrọ yii.

Ki lo n bi awọn eeyan ninu nipa abadofin yii?

Section 98

Abala yii n sọ pe lilo omi yoo nilo gbigba iwe aṣẹ paapaa ko to bẹrẹ iṣẹ akanṣe.

Section 104

Abadofin naa yoo fun ijọba lanfani lati mọ ẹni to ba n lo omi laloju ki ijọba le din iye omi ti idile kan yoo maa ri gba si dede iye ti wọn nilo gẹlẹ.

Section 107

Ijọba yoo lanfani ati fagile iwe aṣẹ bi ẹnikẹni ba n lo omi nilokulo.

Section 120

Awọn ọmọ Naijiria gbudọ gba aṣẹ ki wọn to gbẹ ilẹ fun ẹrọ omi borehole fun owo ṣiṣe tabi fun ile. Wọn gbudọ gba iwe aṣẹ agbẹkanga.

Section 125

Awọn to ba laṣẹ nikan lo le maa ṣamojuto bi awọn eeyan ṣe n lo omi wọn si gbudọ ni kaadi idanimọ.

Section 131

Bi oo ba tẹle awọn ofin yii, oo le lo omi.

Awọn ipinlẹ yoo le ṣamojuto ni aarin ipinlẹ wọn ṣugbọn labẹ ofin ijọba apapọ.

Ẹwẹ, ofin yii ti bori gbogbo ẹtọ ti ẹnikẹni ni tẹlẹ lati lo omi.

Iha wo lawọn eeyan kọ si i?

Gomina Benue, Samuel Ortom ni gbogbo ohun to wa ninu abadofin naa ko ba eyi to wa ninu iwe ofin lilo ilẹ mu torinaa o ni ijọba ni nkan mii ti wọn fẹ ṣe labẹlẹ.

Ọjọgbọn Wole Soyinka kilọ ni tirẹ pe bi wọn ba file buwọlu u, yoo fun aarẹ ni gbogbo agbara lori gbogbo ọna omi lori ilẹ ati labẹ ilẹ.

Bakan naa, awọn ẹgbẹ naa n bu ẹnu atẹ lu u.

Esi ijọba

Minisita eto iroyi ati aṣa, Lai Mohammed ati minisita to n ri si ọrọ omi, Amojuẹrọ Suleiman Adamu ṣalaye pe awọn to n bu ẹnu atẹ lu u ko tilẹ tii joko ka anfani rẹ, wọn kan n ka ohun tawọn eniyan n sọ ni.